Kogi 2023: Kí ni èròńgbà àwọn aráàlú ṣáájú ètò ìdìbò Gómìnà?

Published

Ọpọ awọn eeyan ipinlẹ Kogi lo ni afojusun kan tabi meji ti wọn reti lọwọ ijọba tuntun ti yoo gba iṣejọba lọwọ Gomina Yahaya Bello.

Ọdun kẹjọ ree ti Gomina Yahaya Bello ti n tukọ ipinlẹ Kogi gẹgẹ bi Gomina.

Ileeṣẹ BBC News Yoruba ti balẹ si ipinlẹ Kogi bayii lati mọ bi eto idibo yoo ṣe waye.

Ẹgbẹ oṣelu APC, PDP, SDP ati awọn ẹgbẹ mii ti ṣe ipolongo ibo kaakiri ipinlẹ Kogi, ti wọn si ti bawọn araalu sọrọ pe ki wọn dibo fun wọn.

Ohun gbogbo ti bẹrẹ bayii, Ileeṣẹ BBC Yoruba bawọn araalu sọrọ lori afojusun wọn bi ijọba mii ṣe fẹ gba iṣakoso ipinlẹ Kogi.

Ọpọ eeyan to ba wa sọrọ ni awọn ti ṣetan lati dibo, ti awọn si ni kaadi idibo lọwọ lati yan ẹni ti ọkan wọn fẹ lati jẹ Gomina ipinlẹ Kogi.

Ẹ wo fọnran yii lati gbọ ero awọn araalu ipinlẹ Kogi.