You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Iléèṣẹ́ ọlọ́pàá ti ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Ekiti pa
Ileeṣẹ ọlọpaa ti ti ilẹkun ile aṣòfin ipinlẹ Ekiti pa lẹyin wakati diẹ ti àwọn aṣofin yan olori ile tuntun.
Ọjọ Iṣẹgun ni wọn dibo yan olori ile tuntun lẹyin oṣù kan ti olori ile tẹle, Funminiyi Afuye jáde laye lọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹwaa.
Ọgbẹni Gboyega Aribisogan ni olori ile aṣòfin tuntun ipinlẹ Ekiti, lẹyin to ni ibo mẹẹdogun. Alatako rẹ, Arabinrin Olubunmi Adelugba ni ibo mẹwaa.
Agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, ASP Sunday Abutu, sọ fun awọn akọroyin labẹle pe àwọn ti ile aṣòfin naa pa nitori aṣiri tu pe awọn janduku kan n gbèrò lati kọlu u.
Botilẹ jẹ pe Abutu ko le sọ boya ikọlu naa ni nkankan ṣe pẹlu yiyan olori tuntun, o ni awọn ti n ṣe iwadii orisun idunkooko mọ alaafia ile aṣòfin naa.
Yatọ si àwọn ọlọpaa, àwọn oṣiṣẹ ajọ Civil Defence naa wa nile aṣòfin.
Titi di igba ti àwọn ọlọpaa tíì pa, ko si iroyin wahala kankan lati ile aṣòfin naa. Aṣofin Aribisogan wá lati ẹkùn idibo Ikole. Saa keji si lo n lo lọwọ ninu ile aṣòfin naa.