You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àdó olóró Iran ṣekúpa ọmọ ogún Amẹ́ríkà méjì, ìkọlù bẹ̀rẹ̀ lákọ̀tun
Awọn alaṣẹ orilẹ ede Amẹrika ni awọn tun ti ju ado oloro si awọn ileeṣẹ aabo oju ofurufu ati ori omi Iran ni alẹ ọjọ Abamẹta.
Ileeṣẹ aabo Amẹrika, US Central Command, Centcom sọ pe awọn ọmọ ogun Amerika ṣekọlu sawọn ileeṣẹ Ologun naa, ti ileeṣẹ iroyin Iran naa si fidi rẹ mulẹ pe Amẹrika ṣekọlu si Qeshm Island to wa ni odo Strait of Hormuz.
Centcom tun ni awọn ni afojusun si ṣiṣe ikọlu si Iran's Revolutionary Guard, IRGC, ikọ Ologun Iran to wa nidii ikọlu ti Iran ṣe si Jordan lọjọ Ẹti, eyi to ṣokunfa iku ọmọ ogun Amẹrika meji, ti ọmọ ogun mii si di await.
Lati fesi si ikọlu yii, ileeṣẹ Ologun Iran ni awọn ti ṣekọlu pẹlu duroonu si ibudo Amẹrika meji to wa ni Kuwait.
Amẹrika ati Iran lo ti n ṣe ikọlu sira wọn lemọlemọ lenu ọjọ mẹta bayii, tawọn mejeeji si n fẹsun kan ara wọn pe wọn n ṣe ikọlu sawọn ohun amayedẹrun to wa fun araalu.
Ni ọjọ Abamẹta, Iran ni ohun ṣe ikọlu to lagbara pẹlu duroonu kamikaze si ileeṣẹ Ologun Amẹrika ni ibudo Udairi ati omiran ni ibudo ofurufu Ali Al Salem ni Kuwait gẹgẹ bi ajọ Tasnim ṣe sọ.
Centcom ni tirẹ sọ pe ikọlu ni alẹ ọjọ kẹjọ ti Amẹrika ṣe jẹ ojuna lati din agbara Iran lati dena lilọ bibọ ku ni Strait of Hormuz ni.
Ninu atẹjade kan ti Centcom ti kọkọ fi lede lọjọ Abamẹta sọ pe ọmọ ogun Amẹrika meji lo ba ikọlu Iran lọ lọjọ Ẹti nigba ti ọmọ ogun mii si di await.
Akọwe ileeṣẹ aabo Amẹrika, Pete Hegseth ninu atẹjade to fi soju opo X sọ pe iku awọn ọmọ ogun naa tunbọ mu awọn lọkan le si ni.
Iku awọn ọmọ ogun Amẹrika yii lo sọ ọmọ Amẹrika to ti ba ogun naa lọ di merindinlogun.
Ni ibẹrẹ oṣu yii ni wọn kede riri oku awakọ ikọ Ologun ori omi ọmọ Amẹrika kan ti wọn ti n ṣaaju wa.
Ni Iran ẹwẹ, ko din ni aadọta awọn eeyan to ti padanu ẹmi wọn nigba ti awọn to le ni ẹẹdẹgbẹta ti farapa lẹnu ọsẹ mẹta ti ikọlu tun ti bẹrẹ pada gẹgẹ bi ileeṣẹ eto ilera Iran ṣe sọ.
Awọn orilẹ ede mejeeji lo ti n fẹsun kan ara wọn pe wọn n ṣe ikọlu sawọn ohun amayedẹrun to wa fun araalu amọ Amẹrika ti jiyan eyi, pe awọn ohun to jẹ ti ileeṣẹ Ologun nikan ni wọn n ṣẹ ikọlu si nigba ti Iran si sọ pe wọn ṣe ikọlu si afara ati ibudokọ kan.
Igbimọ awọn orilẹ ede Gulf Cooperation Council fẹsun kan Tehran pe n mọọmọ ṣekọlu si awọn ohun amayedẹrun to wa fun araalu leyin ti Kuwait ni Iran ṣekọlu si ileeṣẹ ohun amuṣagbara ati ileeṣẹ om ikan.
Ṣaaju ni Amẹrika ati Iran ti kọkọ fẹnuko lati dawọ ogun duro ninu oṣu Kẹfa amọ ti adehun naa pada fori sọpan ni ọjọ Kẹjọ, oṣu Keje.