Wò ìgbà tí CBN làwọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní kó owó N100,N200,N500 àti N1000 nílẹ̀

Aworan ẹẹdẹgbẹta Naira

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published

Banki apapọ orileede Naijiria ti kede pe awọn ti ri aṣẹ gba lọdọ aarẹ Naijiria, Muhammadu Buhari lati gbe ẹda owo tuntun mii jade ni Naijiria.

Aṣẹ ti aarẹ fun wọn yi gẹgẹ bi Gomina Banki naa Godwin Emefiele ti ṣe wi,yoo ka owo ọgọrun,igba, ẹẹdẹgbẹta ati ẹgbẹrun Naira to wa nilẹ bayi.

Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ ni ilu Abuja lo fidi ọrọ yi mulẹ.

Emefiele sọ pe aisi owo to tuntun nita jẹ nkan tawọn kọminu lori eleyi to mu ki iyipada ati ipese owo Naira mi ṣe pataki.

O ni lẹnu ọjọ mẹta yi, awọn ti n ri bawọn eeyan ti ṣe n ṣe ayederu owo Naira ni paapa owo ẹẹdẹgbẹta ati ẹgbẹrun Naira.

Nigba wo ni owo tuntun yoo jade?

Emefiele ṣalaye pe lati nkan bi ogun ọdun sẹyin ni iyipada ti de ba owo Naijiria kẹyin.

O ṣalaye pe lagbaye laarin ọdun marun un si ọdun mẹjọ lawọn ijọba maa n gbe owo tuntun jade.

O ni tori eyi ati awọn nkan mii to n lọ lode lo mu ki awọn fẹ parọ owo Naira to wa nita.

Amọ owo tuntun naa yoo bẹrẹ si ni tẹ awọn araalu lọwọ lati ọjọ Kẹẹdogun oṣu Kejila 2022.

Owo ti tẹlẹ nkọ?

Ninu alaye rẹ, o ni owo to wa nita yi yoo ṣi jẹ nina titi di ọjọ kọkanlelọgbọn oṣu Kini ọdun 2023.

O ni bi ọjọ yi ba ko, ẹni ti owo yi ba wa lọwọ rẹ ko ni ri owo ti tẹlẹ na mọ.

Torinaa Emefiele sọ pe awọn banki ko gbọdọ ja owo kankanlori alabara wọn to ba fẹ ko owo pamọ bẹrẹ lati wakati yi lọ.

O ni eleyi yoo fawọn eeyan lanfaani lati ko owo ọwọ wọn to jẹ ti tẹlẹ si ile ifowopamọ ṣaaju ki owo mii to jade.

Ipa tawọn banki ni lati ko ree

Emefiele fi kun alaye to ṣe pe awọn ile ikowopamọ si ni lati ṣe awọn nkan wọnyi ṣaaju ki owo tuntun to gbode:

  • Awọn to ba kọkọ forukọ silẹ ni yoo ri owo tuntun naa gba
  • Awọn banki gbọdọ ṣiṣẹ laarin ọjọ Aje si ọjọ Abamẹta ni paapa ẹka wọn ti yoo ma a gba owo ti tẹlẹ lọwọ araalu.