Nigerian Insurgency: Gómìnà Zulum ṣèkìlọ̀ lórí ìdúnkokò ikọ̀ agbéṣumọ̀mí ISWAP sí Nàìjíríà

Babagana Zulum

Oríṣun àwòrán, @Mohamme17292289

Published

Gómìnà ìpínlẹ̀ Borno, Babagana Zulum tí ṣèkìlọ̀ pé ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Islamic State's West Afica Province (ISWAP) jẹ́ ìdúnkokò ńlá sí orílẹ̀ èdè Nàìjíríà.Zulum pè fún ríró àwọn ọmọ ogun lágbára dáadáa kí wọ́n le dènà ikọ̀ yìí lati hùyẹ́ ju bí wọ́n ti wà lọ.Ó wòye pé bí ISWAP pẹ̀lú gbogbo ohun èlò ìjà tí wọ́n ní bá rí ààyè wọ àárín gbùngún orílẹ̀ èdè Nàìjíríà yóò kó ìnira tó pọ̀ bá àwọn ènìyàn ju ti ikọ̀ agbéṣùmọ̀mí Boko Haram lọ.

Àkọlé fídíò, Adebisi Idikan: Òun ló gba Ìbàdàn sílẹ̀ lọ́wọ́ ìyà owó orí sísan

Zulum sọ̀rọ̀ yìí níbi ìpàdé kan ní ilé Ààrẹ ní Abuja.Bákan náà ní àná, ni ẹ̀ka Nigeria Financial Intelligence (NFIU), ṣàwárí àwọn mẹ́rìndínlọ́gọ̀rún tó ń ṣàtìlẹyìn owó fún àwọn agbéṣùmọ̀mí ní orílẹ̀ èdè yìí pàápàá àwọn tó ń ṣàtìlẹyìn fún ikọ̀ Boko Haram ISWAP.NFIU tún ṣàwárí àwọn 424 tó jẹ́ àwọn alátìlẹyìn wọn, àwọn ilé isẹ́ 123 àti àwọn tó ń ṣe owó 33 tó ní àjọṣe pẹ̀lú àwọn agbéṣùmọ̀mí náà.

Zulum wá rọ Ààrẹ Muhammadu Buhari láti tété wá àtìlẹyìn àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ òkèrè láti kojú ikọ̀ àwọn agbéṣùmọ̀mí náà.Ó ní ìjọba ń ṣe gudugudu méje yàyà mẹ́fa lórí ètò ààbò ṣùgbọ́n omi ṣì pọ̀ lámù, ìpèníjà ṣì pọ̀ fún ìjọba.Ó tẹ̀síwájú ìkìlọ̀ yìí ṣe pàtàkì lójúnà à ti má gba ISWAP láàyè láti rídìí jòkòó ní Nàìjíríà.

Bẹ́ẹ̀ náà ló ní àjọ ọmọ ogun gbọ́dọ̀ tún ìgò wọn fọ̀, kí wọ́n wá ọ̀nà tí wọ́n yóò fi kojú ISWAP.Bákan náà ló tẹmpẹlẹmọ́ ìdí tí Nàìjíríà láti wá àtìlẹyìn ilẹ̀ òkèrè, bó ṣe ní àwọn orílẹ̀ èdè bíi America, Britain àti àwọn mìíràn tí wọ́n lágbára ju Nàìjíríà lọ gan ṣì máa ń bèèrè fún àtìlẹyìn orílẹ̀ èdè mìíràn tí wọ́n bá ní ìpèníjà.Zulum tún pè fún àyípadà àti àtúnṣe sí ètò ìgbanisíṣẹ́ àjọ ọmọ ogun.