You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Cut off Marks: Kíni nkán tí àjọ JAMB n ṣé f'awon akẹ́kọ̀ọ́ àríwá Nàìjíríà tí El Rufai kò dùn inú sì?
Gomina Nasir El-Rufai ti ipinlẹ Kaduna ti bẹnu atẹ lu bi awọn alaṣẹ ẹka eto ẹkọ ṣe n bu maaku fawọn akẹkọọ lati apa ariwa Naijiria.
O ni iyapa laarin maaki awọn akẹkọọ ariwa ati awọn akẹgbẹ wọn da bi fifa ori apa kan si fi ọkan silẹ.
Ninu ifọrọwanilnuwo kan pẹlu ileeṣẹ amohunmaworan Naijiria Channels TV lo ti fi ọrọ yi lede.
El Rufai ni fifun wọn ni odiwọn maaki kekere lati fi gbawọn sile ẹkọ giga, paapa ninu idanwo igbaniwọle si fasiti, JAMB ko dara to.
Koda o ni iru iṣesi bayi ti mu ki awọn akẹkọọ ẹkun Ariwa ya ọlẹ nidi ẹkọ wọn.
El Rufai to ti fi igba kan jẹ Minisita fun olu ilu Naijiiria, Abuja, ṣalaye pe didin maaki awọn akẹkọọ lati Ariwa Naijiria ko ṣe anfaani kankan bi kii ṣe pe o n koba agbegbe naa.
O wa rọ ajọ JAMB paapa lati fopin si iṣesi yi lati ṣe iwuri fawọn akẹkọọ naa lati ''gbaju mọ iṣẹ ki wọn si le figa gbagba pẹlu akẹgbẹ wọn''
''Tipẹtipẹ ni apa ariwa ti n tọ awọn apa yoku lẹyin nidi eto ẹkọ.
"Lati igba ti Naijiria ti gba ominira bo ti ṣe ri nuu.Ko ṣe anfaani kankan fun wa bi kii ṣe pe o mu ki awọn akẹkọọ wa ya ọlẹ''
O ni o yẹ ki wọn gba awọn akẹkọọ niyanju lati mura si ẹkọ ni ati pe awọn yoo bẹrẹ igbaradi fawọn ọmọ Kaduna lati pegede ninu idanwo ti wọn ba kọ.
Lẹnu lọọlọ yi awọn ileẹkọ ti wa ni titi pa ni ipinlẹ Kaduna nitori wahala ijinigbe to n waye ni gbogbo igba.
Gomina El Rufai ni ko ni pẹ tawọn yoo fi ṣi ileẹkọ pada fawọn akẹkọọ lati pada si kilasi wọn.