Aisha Yesufu: Àbúrò ìyá mí tó ti wà di olùṣọ àgùntàn lóni fojú mí rí mọbo

Aisha Yesufu

Oríṣun àwòrán, Aisha Yesufu/Facebook

Published

Yoruba ni oju ẹni maa la, o di dandan ko ri to, bẹẹ ni si ọla ni iyọnu tiẹ.

Bẹẹ ni ọrọ ri nigba ti Aisha Yesufu, to jẹ́ gbajugbaja ajafẹtọ ọminiyan ni Naijiria tẹnu bọ itan igbesi aye rẹ fun awọn akọroyin.

Ninu alaye rẹ, Aisha sọ nipa bi aburo baba rẹ ṣe sọ fún ùn pé kò ni já mọ nkankan laye rẹ.

Ninu ọrọ tó pọ bi igba ti eeyan n kọ episteli to kọ sójú opo ayelujara rẹ, Aisha Yesufu ni ẹni to fi iya jẹ oun ni kekere yii, kii ṣe ara ita si oun rara.

O ni aburo mama oun ẹni naa ṣe ati pe loni bayii, ẹni náà ti di Oniwaasu ọrọ Ọlọrun, ìyẹn ni pé Pasitọ ni.

Àkọlé fídíò, Tunbosun Odunsin: Ẹlẹ́dàá ló fún mi ní tálẹǹtì ẹ̀kún sísun ní ìrọ̀rùn nínú eré tíátà

"Aburo mama mi yii sọ fun emi ati mama mi nisoju iya to bi mama mi pe, osi ni yoo ta wa ku

O sọ ọpọlọpọ nkan ti o jẹ ọrọ kobakungbe fún wa nígbà naa lọhun, amọ mo ti n gbọ ọpọ ninu rẹ tẹlẹ ṣugbọn ti mi o jẹ sọ fún maami."

Aisha Yesufu ni "ọgbẹ ọkàn ni ọrọ naa jẹ nitori o gba omijé loju mama mi"

"Ẹni táa n wí yií, mama mi lo tọ dagba. Nigba ti yóò ṣe igbeyawo ko ni owo ti yóò fi gba ile, koda ọdọ wa ló n gbe.'

Àkọlé fídíò, Kunle Olajide, Akọ̀wé ìgbìmọ̀: Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ọjọ́ ọ̀la yin kò ṣe e fọ́wọ́ ẹ sọ̀yà, ẹ díde

Nigba to bẹrẹ ilé ẹkọ jeleosinmi, Aisha Yesufu ni awọn obi oun lo fún ọkunrin naa lowo to fi bẹrẹ rẹ.

Ko pẹ, bi nkan ṣe yi pada fún wa niyẹn, ti ati gbọ bukata sí nira fún wa, lọdọ aburo iya mi yii ni mo padà wá lọ gbe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Níbẹ ni o ti fi iya jẹ mí, to sí n sọ fún mi pé mi o le jẹ eniyan laye."

Ọrọ pọ ti Aisha Yesufu sọ nípa mọlẹbi rẹ yii amọ o ni oun dupe pe ero rẹ kò padà ṣẹ lori oun.