You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Covid-19 vaccines: Gómìnà Gboyega Oyetọla, aya rẹ̀ Kafayat gba abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19 ní ìpínlẹ̀ Ọṣun
Gomina Gboyega Oyetọla ti ipinlẹ Ọṣun ati iyawo rẹ Kafayat ti gba abẹrẹ ajẹsara COVID-19 nilu Osogbo.
Dokita agba nileekọṣẹ iṣegun oyinbo ti fasiti ipinlẹ Õṣun, Ọjọgbọn Peter Ọlaitan lo gba abẹrẹ naa fun gomina Oyetọla ati iyawo rẹ.
Ni alẹ ọjọ Iṣẹgun ni awọn alaṣẹ ijọba nipinlẹ Osun tẹwọ gba awọn ipin abẹrẹ ajẹsara naa ti wọn fi ṣọwọ sii.
- Ewú ńbẹ! Ẹgbẹ̀ àwọn oṣìṣẹ́ NLC faraya, yóò gùnlé ìyànṣẹ́lòdí lónìí
- Wọ́n jí mi gbé, só mí mọ́lẹ̀ bí ẹ̀ran, fipábámilòpọ̀ láti di aya wọn torí mo jẹ́ Krìstẹ́nì - Ọmọbìnrin ọdún méjìlà
- Ọlọ́pàá tó bá yìnbọn fún àgbẹ̀ Yorùbá yóò kábàmọ́ọ̀, àwọn tó ń gbé AK-47 ni Buhari ní kí ẹ máa pa- Sunday Igboho
- Kí ló gbé Barry Jhay ọmọ Alhaji Sikiru Ayinde Barrister dé gbaga ọlọ́pàá?
- Ewú ńbẹ! Ẹgbẹ̀ àwọn oṣìṣẹ́ NLC faraya, yóò gùnlé ìyànṣẹ́lòdí lónìí
- Kí ló gbé Barry Jhay ọmọ Alhaji Sikiru Ayinde Barrister dé gbaga ọlọ́pàá?
- Wo ohun mẹ́fà tó yẹ kí o mọ̀ nípa ìbọn AK-47
Bakan naa ni igbakeji gomina ipinlẹ Ọṣun, Benedict Alabi at'awọn ọmọ ignimọ iṣejọba ipinlẹ naa pẹlu gba a.
Ipin ẹgbẹrun mẹrinlelọgota ati ojilelugba (64,240) abẹrẹ ajẹsara COVID-19 AstraZeneca ni wọn pin kan ipinlẹ naa.
Ṣaaju gbigba abẹrẹ ajẹsara naa fun gomina Oyetọla ni wọn ti kọkọ gba a fawọn oṣiṣẹ eleto ilera nibẹ gẹgẹ bi ilana ti ajọ ilera alabọde lorilẹede Naijiria, National Primary Health Care Development Agency gbe kalẹ.
Ninu ọrọ rẹ, gomina Oyetọla ṣalaye pe ohun pinnu lati wa lara awọn ipele akọkọ ti yoo gba abẹrẹ naa ni ipinlẹ ọhun lati le fun awọn eeyan ipinlẹ Ọṣun ni idaniloju pe ko sewu pẹlu gbigba abẹrẹ ajẹsara COVID-19 naa.
O wa rọ awọn olugbe ipinlẹ naa lati karamasiki idaabobo ara wọn lọwọ ajakalẹ arun naa nipa titẹle awọn ilana ti awọn onimọ ilera gbe kalẹ.
Akeredolu pẹlu gba abẹrẹ COVID-19, O ni karaalu yago fun gbọyisọyi nipa abẹrẹ ajẹsara COVID-19
Ni ipinlẹ Ondo, gomina Rotimi Akeredolu pẹlu gba abẹrẹ ajẹsara COVID-19 nilu Akurẹ, to si tun gba awọn eeyan ipinlẹ naa niyanju pe ki wọn yẹra fun iroyin gbọyisọyi nipa abẹrẹ ajẹsara COVID-19.
Gẹgẹ bi o ṣe sọ, ko sewu kankan nipa abẹrẹ ajẹsara naa.
Igbakeji rẹ, Lucky Ayedatiwa, at'awọn lọbalọba bii Osewawe tilu Ondo, Oba Dr. Victor Kiladejo, Deji ilu Akurẹ, Oba Aladetoyinbo Ogunlade Aladelusi pẹlu gba abẹrẹ ajẹsara naa nilu Akurẹ.
Ẹgbẹrun mẹtalelaadọrin ati ọrinlelẹẹdẹgbẹta o din mẹwaa (73,570) ni ipin to kan ipinlẹ Ondo lat'ọdọ ijọba apapọ lọjọ Iṣẹgun, ọjọ kẹsan oṣu kẹta ọdun 2021.