You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Kókó ìròyìn t'òní: Awuyewuye Dino Melaye, iléeṣẹ́ ológun lórí ìkọlù Màìdúgùri
Eyi ni awọn akojọpọ iroyin ti toni.
Dino Melaye yóò f'ojú balé ẹjọ̀
Ileeṣẹ ọlọpa ni ipinlẹ Kogi sọ pe oun yoo gbẹ ọmọ ile igbimọ aṣofin Dino Melaye ati awọn afurasi ọdanran mẹrin lọ sile-ẹjọ giga ni Lokoja, Ipinle Kogi ni ọjọ kẹ̀wa oṣu karun ọ̀dun yii.
Awon afunrasi mefa naa fẹsun kan Senato Dino Melaye wipe oun loun ran wọn ni iṣẹ lati fa ijangbọn ni ipinlẹ naa ṣaaju idibo apaapọ ọdun 2019.
Ológun Naijiria: Ènìyàn 28 ló kú nínú ìkọlù Boko Haram
Ilé isẹ́ ológun ti orílẹ̀èdè Naijiria ti sọ wí pé ènìyàn méjìdínlọ́gbọ̀n ló pàdánù ẹ̀mì wọn nínú ìkọlù àwọn ẹsinòkọkú Boko Haram sí agbèègbè ìlà oòrùn Maiduguri, ní ìpínlẹ̀ Borno. ọmọogun Naijiria ló kọjú ìjà sí áwọn ẹsinòkọkú náà, tí wọ́n sì dènà àwọn Boko Haram náà láti agbègbè tí àwọn ènìyàn pọ̀ sí. Ẹ ka ekunrẹrẹ rẹ ni bii
Awọn nkan miran ti ẹ ni lati mọ loni
Gbọ iroyin iṣẹju kan BBC
Fidio wa fun t'oni
Badagry: Ojú ọ̀nà àrèmabọ̀ fáwọn ẹrú tó ń lọ sókè òkun