2022 World Indigenous Language Day: Àwọn ọmọ Yoruba sọ́rọ́ lórí bí èdè náà kò ṣe ní parun
Yoruba bọ, wọn ni ẹni to sọ ile nu, o ṣo apo iya kọ, eyii lo difa fun ijọba ipinlẹ Osun to ṣe akanṣe eto kan lati gbe ede Yoruba larugẹ lonii to jẹ ayajọ ọjọ aṣa nilẹ Yoruba.
Ninu akanṣe eto naa ni awọn ọmọ Yoruba atata kan ti sọ pataki to wa ninu sisọ ede Yoruba, paapaa laarin awọn obi si awọn ọmọ wọn ninu ile.
Gẹgẹ bii ohun ti wọn sọ, o yẹ ki ijọba gbe ofin kalẹ ti yoo kan nipa fun awọn akẹkọọ lati maa kọ ede Yoruba, wọn ko si gbọdọ ni anfani lati wọ ile ẹkọ giga ayafi ti wọn ba pegede ninu ede Yoruba ninu idanwọle aṣekagba SSCE.
Wọn ni ti ijọba ba le maa ṣe eyii, yoo tun awọn ọdọ soke lati kọ ede naa.
Ẹlomiran to tun sọrọ nibi ayẹyẹ ọhun sọ pe ko bojumnu to bi awọn obi kan ṣe maa n sọ ede Gẹẹsi si awọn ọmọ wọn ninu ile.
O ni “Ọpọ obi ni kii sọ ede abinibi si awọn ọmọ wọn ninu ile.”
“Awọn ọmọ wọnyi ti n sọ ede Gẹẹsi nile ẹkọ, iyẹn naa ti to wọn, ko yẹ ki awọn obi tun maa sọ ede Gẹẹsi si awọn ọmọ yii ninu nile lẹyin ti wọn ti n kọ ede Gẹẹsi nile ẹkọ.”
Awọn eeyan naa fẹnuko pe ti awọn obi ode iwoyi ko ba ṣọra, ede Yoruba yoo parun laipẹ.