Èsì ìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo tí INEC kéde ní èèrú nínú, mi ò gbà á wọlé - Asue Ighodalo olùdíje PDP

Àkójọpọ̀ ìròyìn nípa ìdìbò gómìnà ìpínlẹ̀ Edo

Ìsọníṣókí

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Busayo James-Olufade, Afolabi Akinlabi, Funke Adebiyi

  1. Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ jàǹdùkú olóṣèlú méji pẹ̀lú ìbọn

    Awon ibon naa ree

    Oríṣun àwòrán, Nigeria Police

    Àkọlé àwòrán, Awon ibon naa ree

    Ọwọ ọlọpaa ti ba awọn ọkunrin meji kan,Edwin Obanor ati Audu Tajudeen, nipinlẹ Edo.

    Ibọn ilewọ mẹrin ni wọn ba lọwọ wọn lẹyin ti olobo ta awọn ọlọpaa pe janduku to fẹẹ da ibo ọjọ Satide oni yii ru nipinlẹ naa ni wọn.

    Alukoro ọlọpaa Naijiria, ACP Olumuyiwa Adejobi, ṣalaye pe alẹ ọjọ Ẹti, ogunjọ, oṣu Kẹsan-an ọdun 2024, ni ọwọ ba Obanor, olori ẹgbẹ janduku kan, ni wọọdu kẹrin, Eredo.

    Bẹẹ ni wọn mu Tajudeen ni Igara Akoko, Edo. Adejobi sọ pe wọn ti wa ni ahamọ, wọn yoo si foju wina ofin bo ṣe yẹ.

  2. Ètò ìdìbò gómìnà Edo ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹu báyìí

    Awọn oludibo

    Titẹ ika fun awọn oludije ti bẹrẹ bayii ni awọn ijọba ibilẹ kan nipinlẹ Edo.

    Akọroyin BBC sọ pe awọn oludibo ti n dibo ni awọn ibikan, ti ayẹwo orukọ si n lọ ni awọn ibomii.

    Bakan naa ni ajọ to n risi eto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ninu ọrọ ti wọn fi si ori ayelujara wọn ṣalaye pe eto idibo naa bẹrẹ ni deede ago mẹjọ abọ ni ile ẹkọ alakọbẹrẹ Idumebo ni ijọba ibilẹ aarin gbogbo Esan.

    Oludije lati ẹgbẹ oṣelu mẹtadinlogun ni yoo kopa ninu eto idibo naa.

    Asue Igbhodalo lati ẹgbẹ oṣelu PDP, Monday Okpebhholo lati ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress ati Olumide Akpata lati ẹgbẹ oṣelu Labour Party ni awọn to lewaju awọn oludije naa.

    Eto idibo yii yoo waye ni ibudo idibo 4,519.

  3. Ètò àyẹ̀wò orúkọ àwọn olùdìbò ti bẹ̀rẹ̀ ní àwọn ibùdó ìdìbò kan

    Awọn oṣiṣẹ INEC n ṣaalye fun awọn oludibo bi idibo naa yoo ṣe lọ

    Awọn oṣiṣẹ ajọ INEC to n mojuto idibo gomina nipinlẹ Edo ti bẹrẹ si ni ṣe ayẹwo orukọ awọn oludibo, ni awọn ibudo idibo kan bayii.

    Irinajo awọn akọroyin BBC kaakiri ipinlẹ naa fihan pe ayẹwo bẹrẹ ni awọn ibi kan ni bii aago mẹjọ aabọ owurọ.

    Awọn arugbo naa ko gbẹyin nibi idibo naa
    Àkọlé àwòrán, Awọn arugbo naa ko gbẹyin nibi idibo naa
    Awọn oṣiṣẹ INEC
  4. Wámúwámú ni àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò dúró fún ìdìbò nàá, Àwọn àwòrán láti ibi ètò ìdìbò Gómìnà ìpínlẹ̀ Edo

    Gbogbo eto lo ti n to lọwọ ni ipinlẹ Edo fun eto idibo gomina ti yoo waye lonii.

    Awọn araalu nipinlẹ Edo yoo ni anfaani lati yan gomina tuntun ti yoo rọpo Gomina Godwin Obaseki.

    Ileeṣẹ iroyin BBC ti wa balẹ si ipinlẹ Edo nibi ti a ti ma mu bi nnkan se n waye nipjnlẹ naa wa si eti igbọ yin ni yajoyajo

    Awọn oṣiṣẹ alaabo
    Aworan
    Àkọlé àwòrán, Awọn oṣiṣẹ alaabo fi iya jẹ obinrin yii nitori ẹsun pe, o tapa si ofin eto idibo
    Awn oṣiṣẹ ajọ INEC
    Awọn oludibo n wo orukọ wọn
    Àkọlé àwòrán, Owurọ kutu ni awọn oludibo ati oṣiṣẹ INEC ti n jade
    Aworan
    Àkọlé àwòrán, Owurọ kutu ni awọn oludibo ati oṣiṣẹ INEC ti n jade
    Awọn oludibo
    Aworan

    Oríṣun àwòrán, bb

  5. Olúdíje 17 ló ń wọ ìyáàjá fún ipò Gómìnà Edo lónìí

    Awọn oludije ti n de si ibudo idibo

    Lonii, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan an ọdun 2024, awọn araalu kaakiri ijọba ibilẹ to wa ni ipinlẹ Gomina yoo tu sita lati dibo yan gomina tuntun ti yoo rọpo Godwin Obaseki gẹgẹ bi gomina.

    Ajọ eleto idibo lorilẹede Naijiria, INEC ni lakọ ni igbaradi awọn wa lori eto idibo naa, ti wọn si kesi awọn araalu lati jade sita wa dibo nitori ẹtọ wọn ni.

    Oludije mẹtadinlogun, ti mẹrindinlogun ninu wọn jẹ ọkunrin, ti ọkan jẹ obinrin ni wọn n du ipo naa.

    Amọ, mẹta ninu wọn ni ọpọ gbagbọ pe o ṣeeṣe ko jawe olubori ninu eto idibo naa.

  6. Ẹ kaabọ!

    Ẹ ku ojumọ!

    Ẹ kaabọ si ojude ti a ti n mu iroyin wa fun yin nipa bi idibo gomina ṣe n lọ ni ipinlẹ Edo.