You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Akẹ́kọ̀ọ́ FGC Yauri mẹ́ta pàdánù ẹ̀mí wọ́n nígbà t'awọn ológun àti ajínigbe kojú ará wọ́n
Awọn to ba BBC sọrọ sọ pe ninu ikọlu to waye laarin awọn agbebọn yi ati ọmọogun Naijiria ni awọn ọmọ yi ti padanu ẹmi wọn.
Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́
Yetunde Olugbenga and Yemisi Oyedepo
Obasanjo fèsì lórí báwọn ọmọ Nàìjíríà kan ṣe ń pe ààrẹ Buhari ní Jubril ti Sudan
Iyabo Ojo gbé fídíò míì síta nípa Olofana àti ìhùwàsí àwọn onítíátà lẹ́yìn béèlì Baba Ijesha
Ìwọ́de 'Yoruba Nation' foríṣánpọ́n ní ìlú Offa, ẹ wo ohun tó fàá
"A ń sàárò ọgbọ́n ìṣèjọba àti òṣèlú tí Sẹ́nétọ̀ Abiola Ajimobi ni nígbà ayé rẹ̀"
Ọlọ́pàá tó tẹ George Floyed lọ́rùn pa ti rí ẹ̀wọ̀n ọdún méjìlélógún àti oṣù mẹ́fà he l'Amẹrika
Akẹ́kọ̀ọ́ FGC Yauri mẹ́ta pàdánù ẹ̀mí wọ́n nígbà t'awọn ológun àti ajínigbe kojú ará wọ́n, Akẹkọbinrin meji ati ọkun rin kan padanu ẹmi wọn lọwọ ikọlu ajinigbe ati ọmọ ologun Naijiria
Awọn alaṣẹ nipinlẹ Kebbi sọ pe akẹkọọ mẹta ti faragbọta nigba tawọn ajinigbe ati awọn ologun doju ija kọ ara wọn.
Niṣe lawọn ọmọogun yi n gbiyanju lati doola ẹmi awọn akẹkọọ ile ẹkọ FGC Yauri tawọn ajinigbe yi ji gbe.
Awọn obi ati alagbatọ awọn akẹkọọ yi ni o le ni ọgọta akẹkọọ ati olukọ mẹjọ ti wọn ṣi wa ni ahamọ awọna jinigbe wọn yi.
Awọn araalu sọ pe wọn ti gbe oku akẹkọọ obinrin meji ati ọkunrin kan ọhun fawọn obi wọn.
Ohun ta gbọ ni pe akẹkọọ ọkunrin naa faragbọta pupọ ti awn obinrin naa si gbẹmi mi nigba ti wahala irin ninu igbo ti pọju ẹmi wọn lọ.
A gbọ pe ọkan ninu awọn ọmọdebinrin yi ni aarun Asthma ti ko jẹ ko le mi daada.
Kọmisana feto ẹkọ nipinlẹ Kebbi sọ fun BBC pe awọn ologun Naijiria ṣi n tẹsiwaju lati ṣwari awọnajinigbe yi ati pe eeyan mẹfa ni wọn ti ribi doola lati ijọyi.
Ẹwẹ,awọn ọlọpaa ni ipinlẹ Benue sọ pe awọn ti pa awọn afurasi janduku mẹrinla kan ti wọn fẹ gbiyanju lati doju ija kọ agọ ọlọpaa kan ni ilu Katsina-Ala.
Àlàyé rè é lórí bí o ṣe lè gbá owó ìrànwọ́ N50bn COVID-19 tí CBN gbé jáde
Agbébọn 80 tó jí akẹ́kọ̀ọ́ gbé ní Kebbi gbà ìdájọ ikú lọ́wọ́ àwọn ọmọ ogún Nàìjíríà, Awọn ọmọogun Naijiria ṣe ikọlu si agbebọn to ji awọn akẹkọọ FGC Yauri gbe
Iroyin to gbode lati iwọ oorun Ariwa Naijiria sọ pe awọn agbofinro ti ṣekupa o kere tan awọn ajinigbe ọgọrin lara igbiyanju lati doola awọn akẹkọọ tawọn alaburu yi ji gbe.
Bi a ko ba gbagbe ni Ọjọbọ lawọn olubi wọn yi yabo ile ẹkọ FGC Yauri lọsan gangan ni Kebbi ti wọn si ji awọn akẹkọọ ati olukọ gbe.
Ninu ikọlu to waye, awọn agbofinro ribi doola diẹ lara awọn akẹkọọ taa n wi yi ati awọn olukọ kọọkan.
Awọn ti ọrọ naa ṣoju wọn fi to BBC leti pe awọn foju ri oku awọn janduku to le ni ọgọrin ninu igbo ti wọn pa wọn si.
Wọn fikun ọrọ wi pe ikọlu ṣi n lọ lọwọ laarin awọn agbofinro ati awọn ajinigbe yi ninu igbo kijikiji to wa ni ijọba ibilẹ Sakaba ni Kebbi.
Awọn to ba BBC sọrọ tun ṣalaye pe niṣe lawọn agbebọn to ji eeyan gbe yi bori awọn ọlọpaa to n ṣọ ileewe naa ti wọn si gba ọkọ Hilux kan ti wọn fi ko awọn akẹkọọ yi si.
Ọpọ awọn akẹkọọ lo ti n gba itọju nile iwossan nitori ifarapa to waye lasiko ikọlu si ileewe wọn.
Muhammad Bello Ingaski, aṣofin to n ṣoju agbegbe naa lo ti ṣaaju fidi iṣẹlẹ yi mulẹ fun BBC Hausa pe awọn ajinigbe yi ji akẹkọọ ọkunrin ati obinrin gbe lỌjọbọ.
Ó ṣeéṣe kí Ààrẹ Biden má ní àǹfààní láti jẹ ''oúnjẹ alẹ́ Oluwa'' nítorí o fàyè gba oyún ṣíṣẹ́
O ṣeeṣe ki aarẹ orilẹede Amerika, Joe Biden ma le e jẹ ounjẹ alẹ Oluwa lẹyin ti Ijọ Aguda lorilẹede Amerika dibo lori boya awọn to faramọ oyun ṣiṣẹ le e jẹ ounjẹ alẹ Oluwa.
Nibi ipade ti awọn Bisọọbu Ijọ Aguda ṣe ni ilẹ Amerika ni idibo naa ti waye lati fi gbedeke le awọn oloṣelu to n satilẹyin fun eto oyun ṣiṣẹ lorilẹede naa.
Jijẹ ounjẹ alẹ Oluwa jẹ ọkan pataki ninu eto ilana ijọ Aguda kaakiri agbaye.
Awọn bisọọbu ilẹ Amẹrika naa ni awọn eniyan 168 si 55 lo buwọlu idibo naa, ti ipele keji yoo si waye nibi ipade gbogboogbo ti yoo waye ni Oṣu Kọkanla, ọdun 2021.
Ninu ọrọ rẹ, aarẹ Joe Biden to jẹ aarẹ keji lorilẹede Amẹrika ti yoo jẹ ọmọ ijọ Aguda sọ wi pe igbesẹ awọn bisọọbu naa ko le e kẹsẹjari.
Biden ni ''ọrọ idakọnkọ ni iṣẹlẹ naa, ti mo si gbagbọ wi pe ko si oun to jọ bẹẹ pe nko ni le e jẹ ounjẹ alẹ Oluwa nitori mo faramọ ki ẹni to ba fẹ ṣe oyun ni anfaani lati ṣẹ ẹ lai si idiwọ.
Amọ, iroyin ni o ṣeeṣẹ ki ajọ oludari ijọ Aguda lagbaye, Vatican bu ẹnu atẹ lu igbeṣẹ awọn bisọọbu lorilẹede Amerika naa.
Bakan naa ni ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan ni Ijọ Aguda to n jafun ẹtọ si oyun ṣiṣẹ, Catholics for Choice ni inu awọn bajẹ gidigidi si igbeṣẹ awọn bisọọbu wọnyii nitori iwa naa ko bojumọ, ti ko si dabi ẹni pe awọn Bisọọbu naa hu iwa bi Ọlọrun.
N5M ni a pàdánù lásìkò tí ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo lé wa kùró ní Sabo - Àwọn oníbárà
A ó sọ ibùdókọ̀ ojú irin ìlú Ibadan di gbàgede káràkátà láìpẹ́ - Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo
Wo iye owó tí ìjọba Naijiria ti yá lọ́wọ́ China láti ìgbà tí Ààrẹ Muhammadu Buhari ti gorí àléfà
Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ́ 70 ké sí ìjọba Naijiria láti yí ìpinnu rẹ̀ padà lóró òfin tó fi de Twitter
Wọ́n gbé Bobrisky dìgbà-dìgbà padà sílé ìwòsàn lẹ́yìn iṣẹ́ abẹ ìdí
Kò sí ìjà kankan láàrín èmi àti Saheed Osupa - Muri Thunder
À ń ṣe ara wa ni Bí a bá kọ̀ láti máa lo egbòogi igbó ní Naijiria - Akeredolu
Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàwárí ibi tí wọ́n ti ń rọ ìbọn AK-47 lábẹ́lé ní Jos
Ṣé lóòtọ́ ni wọ́n fipá bá akẹ́kọ̀ọ́ UNILORIN lòpọ̀ títí tí ẹ̀mí fi bọ́ lára rẹ̀?
Ilé ẹjọ́ sún ìdájọ́ ẹjọ́ tí Jegede pè tako ìbò tó gbé Akeredolu sípò gómìnà lẹ́ẹ̀kejì síwájú