You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Ìjíròrò láàrin àwọn olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ

Ìròyìn àti àlàyé lórí ìjíròrò láàrin àwọn olùdíje sípò gómìnà ìpínlẹ̀ Ọyọ láti gbàngàn UCH ní Ibadan

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Abdulwasiu Hassan

  1. Akala lórí ètò ẹ̀kọ́ àti Lautech

    Ni gbogbo orilede Naijiria Oyo state lo ni aabọ fasiti. O ni bi oun ba de.iṣejọba oun yoo gba fasiti Lautech pada fun ipinlẹ Oyo.

    Akala ni oun yoo seto eko ofe to munadoko fun awon ileewe aladani ati ti ijọba

  2. Akala lórí ìrírí òṣèlú

    Akala ni iriri oselu Naijiria see mu yangan paapaa fun awon to ba see pẹlu Iberu Ọlọrun. Akala tun salaye pe oselu isẹyin ko nilo baba isalẹ.

  3. Adelabu lórí ìrírí òṣèlú

    Adelabu ni ọrọ iriri oselu Naijiria ko see mu yangan. O ni oselu jagidijagan ati owo ni o gbilẹ ni Naijiria. O ni lootọ ni atari ajanaku kii ṣe ẹru ọmọde sugbon iriri aye ni wọn nsọ, kii se ọjọ ori. O ni awon orilede okeere awọn ọdọ lo n sejoba

  4. Sarumi lórí ìrírí òṣèlú

    Bolanle Sarumi-Aliyu ni lootọ ni irir eto oselu Naijiria ko ṣee mu yangan. O ni awọn ijọba maa n si isuna pin to si n da nnkan ru. Lori atari ajanaku o ni ki ẹnikẹni maa lo ọrọ ọjọ ori lati de awọn ọmọde lona

  5. Lanlehin lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú Nàìjíríà

    Lori oro se iriri oselu Naijiria see mu yangan Idahun Lanlehin ni pe oun ko faramọ ati pe awọn eeyan Naijiria naa ni yoo see daadaa. Lori atari ajanaku o ni oun fara mọ nitori eeyan ni lati gbe ese nikookan

  6. Bolanle Sarumi-Aliyu

    Ibeere fun sarumi ni pe se o lero pe ipinlẹ Ọyọ ṣetan fun uipo gomina nipinlẹ Ọyọ. O si dahun pe awọn obinrin ti ṣetan fun ipo yii ati pe oun pẹlu ti ṣetan. "Mi o ni ile rẹpẹtẹ ṣugbọn mo ti ṣọ eeyan rẹpẹtẹ di nla"

  7. Akala lórí ọjọ́ orí

    Ibeere fun Akala nipe o ti da gba ki lo tun n wa. Akala dahun pe ko yẹ ki ọjọ ori jẹ idena. O ni "ọrọ ipinlẹ Ọyọ atari ajanaku ni kii ṣe ẹru ọmọde". O ni Nibi ti ọrọ de duro, ipinlẹ Ọyọ nilo eeyan to nilo iriri

  8. Adelabu lórí ìrírí òṣèlú

    Ibeere fun Adelabu lori idi ti ko fi bere ni ibẹrẹ akasọ oṣelu. Adelabu ni looto oun ko ni iriri ninu oṣelu "sugbon iriri oṣelu orileed Naijiria ko ṣe mu yangan. O nigege bii igbakeji akowe banki apapọ tẹlẹ, gomina ipinlẹ ko lee ṣoro

  9. Lanlehin lórí bàbá ìsàlẹ̀

    Ibeere fun Lanlehin nipa baba isalẹ. O ni oun ko mọ nipa baba isalẹ kankan. Amoṣa o ni ko si ẹni lee yọ ọwọ awọn agbalagba kuro ni eto oselu nitori ọmọde gbọn agba gbọn la fi da ilẹ ifẹ.

  10. Adelabu lórí àbò

    Adelabu ni ohun meji ni oun yoo ṣe. Didena ati idojukọ ipenija abo. Iṣẹ agbẹ, iṣẹ ọwọ ati ere idaraya fawon ọdọ yoo din wahala ipenija abo ku

  11. Akala lórí àbò

    Alao Akala ni gẹgẹ bii Ọlọpaa to ti feyinti oun mọ ọna abayọ si ipenija ọrọ abo. Oun yoo ṣiṣẹ pọ pẹlu awọn agbofinro lati mu eto abo gbopọn sii.

  12. Lanlehi lórí ọ̀rọ̀ àbò

    Lanlehin ni lori eto abo ni ohun to n fa wahala ni ilu yoo gba amojuto nipa ipese iṣẹ. "Ko si ẹni fẹ ṣe jagidijagan to ba ri iṣẹ ṣe." O ni eto idaṣẹsilẹ, eto ọgbin ati ileeṣẹ kereje fun igbaniisiṣẹ.

  13. Sarumi lori eto abo

    Sarumi ni aisi olori gidi ni kii mu ki ilu toro. O ni ko lee si abo laisi iṣẹ. O ni oun yoo ro awọn ọdọ lagbara.

  14. Akala lórí ètò ìlera

    Alao Akala ni saa isejoọba oun akọkọ ohun da awọn eto ilera alabode ẹsẹ kuku silẹ. O ni ni ile iwosan nla Adeoyo ko sí ẹrọ amunawa to dara. Ati pe ohun yoo ṣe agbekalẹ ilera ọfẹ

  15. Sàrùmí lórí ọ̀rọ̀ ìlera

    Bolanle Sarumi ni gbogbo awon ọmọ wẹwẹ ti ọjọ ori wọn ko ju marun lọ yoo gba eto ilera ofe. Bakan naa ni awon arugno ti ọjọ ori wọn ko din ni odun marundinlaadota yoo maa janfani eto ilera ọfẹ bi oun ba wọlé

  16. Lanleyin lórí ọ̀rọ̀ ìlera

    Lanlẹhin ni tirẹ salaye pe nitori bi ipinlẹ Ọyọ ṣe tobi kun ara ohun to n fa ipenija eto ilera. Nitori naa iṣejoba oun yoo pese ileewosan alabọde kaakiri wọọdu

  17. Adelabu lórí ètò ìlera

    Lori ọrọ eto ilera Adelabu ni ilera je ara ohun meta to la kale. Iṣẹ agbe, eto ẹkọ ati ilera.

    O ni oun yoo tun awọn ile iwosan ṣe ko pada si bo ti wa tẹlẹ.

    O ni isejoba oun yoo mojuto ilera alabọde. Oni iṣejọba oun yoo da ilewosan alabode si gbogbo ijọba ibilẹ

  18. Oluwaseyi Abiodun Makinde,Olùdíje Ìpo Gómìnà lábẹ́ àsìá PDP

    Ọjọ ikẹẹdọgbọn oṣu kejila ọdun 1967 ni wọn bi Oluwaseyi Abiodun Makinde si idile oloogbe Pa Olatunbosun Makinde ati iyaafin Abigael Makinde ni agbo ile Aigbọfa Oja'aba, ilu Ibadan.

    -Ile iwe Girama ti Bishop Phillips Academy ni Monatan, Ibadan lo lọ.

    -Ni ọdun 1985, o gba oye Bachelor's degree ninu imọ ẹrọ, Electrical Engineering lati fasiti ilu Eko

    -Makinde ṣe agunbanirọ ni ile iṣẹ epo Shell lọdun 1990, lati ibẹ lo ti bẹrẹ iṣẹ nipa biboju to oniruuru ẹka ile iṣẹ epo naa.

  19. Sẹnẹtọ Olufemi Lanleyin ẹgbẹ́ òṣèlú ADC

    - Wọ́n bí ní ọjọ́ kẹẹ̀jọ oṣù keèje ọdún 1953 - Wọ́n bíi sí dílé Lanlẹhin ti ìlú Ibadan - Amofin àti olóṣèlú níí ṣe- O jẹ Sẹ́nétọ̀ ilé aṣòfin àgbà keèje - Akẹ́kọ̀ọ́gboyè nínú òfin láti fástì,University of Nigeria Nsukka níí ṣe

  20. Christopher Alao Akala Olùdíje lábẹ́ àsìá ẹgbẹ́ òsèlú ADP

    Wọ́n bíi ní ọjọ́ kẹẹ̀ta oṣù kẹẹ̀fà ọdún 1950 - Akala ti jẹ Gómìnà Ìpínlẹ̀ Ọyọ tẹ́lẹ̀ rí lábẹ́ẹ àsìá ẹgbẹ́ òṣèlú PDP- Ọmọ ogbomoṣọ ni ní Ìpínjlẹ̀ Ọyọ - Ó ṣiṣẹ́ Ọlọ́pàá de ibi tó làmì kótó fẹ̀yìntì nídi iṣẹ́ náà lọ́dún 1995- O tun gba iwe-ẹri ninu amojuto okowo

    - Onisowo pataki nii ṣe ti o si j oludasilẹ ile iṣẹ Radio Parrot FM Ogbomosho