You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.

Take me to the main website

Wo bí àjọyọ̀ ṣe ń lọ lọ́wọ́ ní Kogi 'toríi Yahaya

Ẹ kaabọ si oju opo BBC Yoruba. Wọnyii ni ohun ti awọn akọ̀ròyìn wa to ti wa ni ikalẹ ni ipinlẹ Kogi ati Bayelsa.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Yetunde Olugbenga

  1. Bi idibo yoo ti ṣe lọ, Ilana ti INEC la kalẹ fun idibo nipinlẹ Kogi re e

    Ajọ Eleto Idibo, INEC ti ni aago mejọ aarọ si meji ọsan ni ayẹwo orukọ yoo bere

    Ẹni ti o ba de agọ idibo ki aago meji ọsan to lu ni wọn yoo fun laaye lati dibo.

    Kaadi idibo ni wọn yoo lo lati fi se idibo naa.

    Osisẹ Ajọ INEC yoo beere kaadi idibo rẹ lati se ayẹwo orukọ rẹ boya o fi orukọ silẹ.

    Wọn ti kilọ fun awọn eniyan lati fi ago idibo silẹ ni kete ti wọn ba ti dibo wọn tan.

    Ko gbọdọ si lilo ẹrọ ibanisọrọ ni ayika ibi ti idibo ba ti n lọ lọwọ.

  2. Kogi vs Bayelsa: Irọ́ ni pé wọ́n sèkọlù sí Gómìnà Seyi Makinde - Ọlọ́pàá Kogi, Wọ́n o sèkọlù sí Gómìnà Seyi Makinde-Ọlọ́pàá Kogi

    Kọmisọnna Ọlọpaa ni ipinlẹ Kogi, Hakeem Busari ti ni irọ ni pe wọn se ikọlu si Gomina ipinlẹ oyo, Seyi Makinde ni ilu Lokoja.

    Busari fi idi ọrọ yii mulẹ lasiko to n ba ikọ BBC sọrọ lori ẹrọ ipanisọrọ rẹ.

    O ni ko si otitọ kankan ninu ọrọ to n kaakiri naa.

    Seyi Makinde ni Alága ẹgbẹ́ òsèlú PDP fún ètò ìdìbò sípò gómìnà tí yóò wáyé ní Ọjọ Kẹrindinlogun, Osu Kọkanla, odun 2019.

  3. Ọlọ́pàá 35,800 ló ti dé sí ìpínlẹ̀ Kogi láti pèsè ààbò- Kọmíṣọ́nnà, Kogi àti Bayelsa 2019: ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ náà ti fọ́nká sí ìgboro Kogi

    Kọmiṣọnna àwọn ọlọpaa ni ipinlẹ Kogi ní pé kò séwu lóko loungẹ fawọn oludibo ni Kogi nitori pe àwọn n ṣiṣẹ bó ti yẹ.

    Kọmiṣọnna Hakeem Busari ṣalaye fun BBC pe, gbogbo eto ti to lori idibo lonii kaakiri ipinlẹ Kogi

  4. Kogi 2019 Election: Olùdíje 24 ni yóò kópa ní ìdìbò Kogí

    Ẹgbẹ oselu APC ati PDP lo jẹ gboogi ninu ẹgbẹ oselu mẹrinlelogun to n kopa ninu idibo sipo gomina ni ipinlẹ Kogi.

    Natasha Akpoti ti ẹgbẹ oṣelu SDP ni obinrin kan ṣoṣo to n dije dupo Gomina.

    Gomina Yahaya Bello ni Gomina to wa lori aleefa ti o si tun jẹ Gomina ti ọjọ ori rẹ kere julọ ni Naijiria.

  5. Lóni ní ọjọ́ a n retí dé ní Kogi àti Bayelsa, Ẹkú ojumọ ẹ sí káàbọ̀ sí ojú òpó BBC Yorùbá

    Ẹṣeun ti ẹ darapọ mọ wa.

    Adajọ ọjọ pe ti Idibo Gomina ni Kogo ati Bayelsa yoo si gbera sọ loni .

    Idibo yi jẹ eleyi ti pupọ eeyan ti n reti lati mọ ẹni ti yoo jaweolubori.

    Ikọ BBC ti wa ni awọn ipinlẹ mejeeji lati mu tifuntẹdọ gbogbo ohun to n waye nibẹ wa si eti igbọ yin.

    Ẹ ma bawa kalọ