Lọjọ Kejilelogun, oṣu kọkanla ni ajọ eleto idibo Naijiria, INEC kede esi idibo nini ijọba ibilẹ mọkanlelogun ni Kogi pẹlu ero pe o ṣeeṣe ki iṣẹlẹ ija wa.
Ọmọọba Abubakar Audu ti APC ni INEC kede 240, 867 fun nigba ti Captain Wada Idris to jẹ gomina tẹlẹ ni PDP ni 199, 514 nipo keji.
Ogbeni Emmanuel Kucha to jẹ adari eleto idibo lasiko naa fun ipinlẹ Kogi sọ pe idibo naa ko kẹsẹ jari bo ṣe yẹ nitori pe ibo 41, 353 lo wa laarin awọn mejeeji bẹẹ ibo 49, 953 ni wọn wọgile ni eyi to fi jẹ pe ibo ibuso idibo mọkanlelaadọrun un ni wọn ṣi nilo.
Leyin eyi ni ọgbẹni Kucha kede esi pe APC ni 6, 885 ibo ti apapọ ibo APC fi jẹ 247, 752.
Nigba ti PDP ni 5, 363 ninu atundi ibo mọ eyi to wa nilẹ to fi jẹ 204, 877 ibo lapapọ.
Lẹyin iku Abubakar Audu to dupo labẹ APC ni APC fa Yahaya Bello kalẹ ti wọn si kede Yahaya Bello lọjọ kejilelogun, oṣu kọkanla.
APC ni wọn gbee fun Yahaya Bello tori oun lo ṣe ipo keji Audu laisko idibo abẹlẹ ninu ẹgbẹ APC.