Àwọn ọmọ ilé aṣòfin mẹ́tàléláàdọ́ta fi APC sílẹ̀

À n mú ìròyìn wá fún yín lórí bí iléèṣẹ́ ọlọ́pà ṣe dí ẹnu ọ̀nà ilé Bukọla Saraki, àti ìjà tó n wáyé láàrin òun àti ìṣàkóso Muhammadu Buhari

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Busayo Akogun

  1. Àwọn ọlọ́pà yíì ilé Saraki po

    Ileeṣẹ ọlọpa Naijiria yii ile Aarẹ ile aṣofin agba Naijiria po ni owurọ kutu-kutu oni.

    Agbẹnusọ rẹ, Bamikọle Omisore fi awọn aworan kan sita loju opo Twitter rẹ pe, awọn ọlọpa di ẹnu ọna ile Saraki.

    Ọkan lara awọn amugbalẹgbẹ Saraki sọ fun BBC pe, aarọ kutu ni awọn ọlọpa de si ile naa to wa ni adugbo Maitama, lopopona Lake Chad, nilu Abuja.

  2. Ẹ káàbọ̀ sí BBC Yoruba. À n mú bí nkan ṣe n lọ lórí ìjà òṣèlú tó n wáyé ní Nàìjíríà wá fún yín.