Ìdìbò Èkìtì lọ ‘wọ́ọ́rọ́wọ́’

A ń mú ètò gbogbo bó ṣe ń lọ níbi ìdìbò fún ipò gómínà káàkiri ipinlẹ Ekiti.

Ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ tí ń lọ lọ́wọ́

Olubusola Afolayan and Adedayo Owolabi

  1. Kókó, Àwọn Janduku ti dojú àpótí ìdìbò bolẹ̀ ní Emure Ekiti

    Àwọn ajo olopaa ni awọn ń wa awọn janduku ti wọn doju apoti ibo bolẹ̀ ni Ward 6 Emure Ekiti.

    Àwọn Janduku ti dojú àpótí ìdìbò bolẹ̀ ní Emure Ekiti
    Àkọlé àwòrán, Àwọn Janduku ti dojú àpótí ìdìbò bolẹ̀ ní Emure Ekiti
    Àwọn Janduku ti dojú àpótí ìdìbò bolẹ̀ ní Emure Ekiti
    Àkọlé àwòrán, Àwọn Janduku ti dojú àpótí ìdìbò bolẹ̀ ní Emure Ekiti
  2. Ọ̀rọ̀ mi di lẹ́yìn ìdìbò- Kayọde Fayẹmi

    Oludije si ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC, John Kayode Fayemi ni eto idibo lọ ni irọwọrọsẹ, amọ O fi kun pe iroyin lati ọdọ awọn Asoju rẹ̀ fi han pe kaadi idibo wọn ko sisẹ.

    Àkọlé fídíò, Oludije si ipo gomina labẹ ẹgbẹ oselu APC, John Kayode Fayemi ti dibo ni wọọdu rẹ.
  3. Ṣẹgun Oni ti dìbò ní ìfàkì Ekiti báyìí

    Ṣẹgun Oni, gomina ipinlẹ Ekiti nigba kan ri naa ti dibo nilu rẹ̀, Ifaki Ekiti.

    Ṣẹgun Oni ti dìbò ní ìfàkì Ekiti báyìí
    Àkọlé àwòrán, Ṣẹgun Oni ti dìbò ní ìfàkì Ekiti báyìí
  4. Ọlọ́pàá ń wòran bí wọ́n ṣe ń pin N4000 - Eleka

    Ẹleka ba BBC sọrọ pe niṣe lawọn ọlọpaa n woran nigba tawọn oloṣelu n pin owo fawọn oludibo lanaa.

    BBC ti kọkọ gbe fidio naa sita to ṣafihan bi awọn oludibo ṣe n sare lọ gba N4000.

    Àkọlé fídíò, Ekiti Election: PDP kọ́ ló ń fún olùdùbò lówó
  5. Kókó, Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ogun ti ya wọ Ekiti

    O le ni ogun bọ́ọ̀si ọkọ̀ ologun to kó àwọn ọmọ ogun wọ Ado Ekiti nisiyi.

    Akoroyin BBC ri wọn lopopona ọja Ọba.

    Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ogun ti ya wọ Ekiti
    Àkọlé àwòrán, Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ogun ti ya wọ Ekiti
    Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ogun ti ya wọ Ekiti
    Àkọlé àwòrán, Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn ọmọ ogun ti ya wọ Ekiti
  6. Kókó, Ẹlẹka ti dìbò láì lo ẹ̀rọ kaadi idibo

    Lẹyin ti ẹrọ kaadi idibo kọ ọwọ́ Eleka ni awọn ajọ INEC jẹ kó lo dibo lai lo ẹrọ kaadi idibo

    Ẹlẹka ti dìbò láì lo ẹ̀rọ kaadi idibo
    Àkọlé àwòrán, Ẹlẹka ti dìbò láì lo ẹ̀rọ kaadi idibo
    Ẹlẹka ti dìbò láì lo ẹ̀rọ kaadi idibo
    Àkọlé àwòrán, Ẹlẹka ti dìbò láì lo ẹ̀rọ kaadi idibo
  7. Ẹ̀rọ káàdì ìdìbò kọ ìyàwó Fayẹmi

    A tun ti gbọ bayii pe iyawo Kayọde Fayẹmi ko lee dibo nitori ẹrọ to n yẹ ika oludibo wo naa tun kọ ika iyawo Fayẹmi gẹgẹ bo ti se fun Olusọla Ẹlẹka. Fayẹmi ati iyawo rẹ ti wa pada si ile wọn bayii.

    Ẹ̀rọ káàdì kọ ìyàwó Fayẹmi
    Àkọlé àwòrán, Ẹ̀rọ káàdì ìdìbò kọ ìyàwó Fayẹmi
  8. Wọ́n ń retí Fayoṣe ni Afao Ekiti

    Ki agogo mẹjọ to lù ni ilu Afao Ekiti to jẹ ilu gomina Fayoṣe lawon oludibo ati oṣiṣẹ INEC ti wa nikale lati bẹrẹ idibo, woorowo nidibo n lọ nibẹ, gomina Ayodele Fayose ko tii jade wa dibo. Awon oludibo to ba BBC sọrọ ni inú àwọn dun bi o ṣe ri yii pelu ireti pe bee ni yoo se ri de opin. Yatọ si awọn iṣẹlẹ diẹ pẹlu ẹrọ ayekawo ti ko tete ri awọn ika kan sugbon lẹyẹ o ṣoka ni awọn onimọ ẹrọ àjọ INEC ti wa ojuutu sii.

    Àkọlé fídíò, Ekiti Election: Idibo ti bẹrẹ ni pẹrẹwu!
  9. Adeniyi Adebayọ: Ọlọ́pàá ló jẹ́ kí àwọn olùdìbò Ekiti jáde dìbò

    Adeniyi Adebayọ, Gomina tẹ́lẹ̀ ní ìpinlẹ Ekiti, ti sọ ni wọọdu idibo rẹ pe eto idibo naa n lọ ni pẹlẹ-putu, ti ko si si wahala kankan.

    Bakan naa lo ni awọn ọlọpaa n sisẹ wọn bo ti yẹ, ti diduro wọn lawọn ibudo idibo si n se iwuri fun awọn oludibo lati jade wa.

    Àkọlé fídíò, Ekiti Election: Niyi Adebayọ ní ohun gbogbo ń lọ létò-létò
  10. Àwòrán àwọn olùdìbò Ekiti tó ti jáde síta

    Awọn wọnyii ni oludibo loriṣiiriṣii to ti jáde sita wa dibo kaakiri ijọba ibilẹ Ekiti

    Àwọn oludibo ń yẹ orukọ wọn wò lara ogiri
    Àkọlé àwòrán, Àwọn oludibo ń yẹ orukọ wọn wò lara ogiri
    Àwọn oludibo ń yẹ orukọ wọn wò lara ogiri
    Àkọlé àwòrán, Àwọn oludibo ń yẹ orukọ wọn wò lara ogiri
    Awọn oludibo ni Ekiti
    Àkọlé àwòrán, Awọn oludibo ni Ekiti
    Iya agbalagba to ń dibo
    Àkọlé àwòrán, Iya agbalagba to ń dibo
    Awọn Oludibo
    Àkọlé àwòrán, Awọn Oludibo
  11. Ìyá ọgọrun ọdún mú kaadi ìdánimọ̀ wá dìbò

    Bakan naa ni awọn oludibo kan ko lee dibo ni awọn wọọdu kan nitori pe kaadi idibo ti ọjọ ti lọ lori rẹ ni wọn mu wa si ibudo idibo.

    Lara wọn ni mama ọgọrun ọdun kan, to jade wa dibo, mama Comfort Ibiyẹye Bọdunde, to jẹ pe kaadi idanimọ lo mu wa dipo kaadi idibo.

    Mama agba Abọdunde wa gba awọn oloselu nimọran lati ma ṣe da rogbodiyan silẹ, amọ ki wọn jẹ ki alaafia jọba lasiko eto idibo naa.

    Mama Comfort Ibiyẹye Bọdunde
    Àkọlé àwòrán, Mama Comfort Ibiyẹye Bọdunde
    Kaadi idibo atijọ ti Mama mú wa.
    Àkọlé àwòrán, Kaadi idibo atijọ ti Mama mú wa.
  12. Kayọde Fayẹmi àti ìyàwó rẹ̀ ti dé sí ibùdó ìdìbò wọ́ọ̀dù

    Oludije fún ipò gomina fẹgbẹ oṣelu APC, Ọmọwe Kayọde Fayẹmi àti iyawo rẹ̀ naa ti de si ibùdó idibo wọọdu rẹ̀ lati wa dibo.

    Ọpọ eeyan lo tẹle e lẹyin, to si ti se ayẹwo orukọ rẹ.

    Kayọde Fayẹmi ti dé sí ibùdó ìdìbò
    Àkọlé àwòrán, Kayọde Fayẹmi ti dé sí ibùdó ìdìbò
    Fayemi de sibudo idibo
    Àkọlé àwòrán, Fayemi de sibudo idibo
  13. Kókó, Oluṣọla Eleka kò lè dìbò

    Iroyin to n tẹ wa lọwọ ni pé oludije fun ẹgbẹ oselu PDP, Ọjọgbọn Olusọla Ẹlẹka ko tii lee dibo ni wọọdu rẹ̀.

    Amọ, a gbọ pe ẹrọ naa gba ika iyawo rẹ, to si ti dibo.

    Oluṣọla Eleka kó tó dìbò

    Oríṣun àwòrán, bbc

    Àkọlé àwòrán, Oluṣọla Eleka kó tó dìbò
  14. Ètò àyẹ̀wò àwọn olùdìbò Ekiti kọjá bẹ́ẹ̀

    Lati ìdájí ni awọn eniyan ipinlẹ Ekiti ti n jade sita, ti wọn n rin lo si ibudo idibo kaakiri nipinle naa fun ayẹwo orukọ wọn lati fi dibo. O lé ni ọtale lẹgbẹrun lọna ọgọrun mẹfa (667,270) oludibo ni ti wọn ti forukọ silẹ pẹlu ajọ eleto idibo INEC lati dibo loni nipinlẹ Ekiti.

    Èrò púpọ̀ jáde wa dìbò l'Ekiti lónìí
    Àkọlé àwòrán, Èrò púpọ̀ jáde wa dìbò l'Ekiti lónìí
  15. Láti ilé agódo ilé akéde BBC Yorùba la ti ń ki gbogbo ẹ̀yin olólùfẹ́ wa pe Ẹ kaabọ sórí ètò akànṣe fún ètò ìdìbò Ekiti ni Nàìjíríà. Etò yii ni a gbé kalẹ̀ fún ìgbádùn yin loni ti a o ti máa mú gbogbo nkan to n ṣẹlẹ nipinlẹ Ekiti wa fún yin. Emi Olubusọla Afọlayan ni atọ́kùn yín fún òwúrọ̀ yii. Gbogbo àwòrán, fídíò àti ifọrọwanilẹnuwo pẹlu awọn eekan ninu oṣelu lọkan kò jọkan ni a o maa mu wa.