Wọ́n de àwọn ènìyàn lọ́nà àti wọlé Abiọla
Ń se ni ìta ilé olóògbé Moshood Kashimawo Ọlawale (MKO) Abiọla kún pitimu fún onírúurú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ̀ọ́ ẹni, tí wọn máa ń wá se ìrántí rẹ̀ ní àyájọ́ ọjọ́ kejìlá osù kẹfà ọdọọdún. Sùgbọ́n fún ìyàlẹ́nu, wọn kò jẹ́ kí wọn wọlé nítorí àwọn gómìnà mẹ́rin ló ń bọ̀ wá lọ́dún yìí láti wá se ìrántí náà






