Ǹjẹ́ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lágbára láti mú olórí Hamas àti Israel?

Oríṣun àwòrán, Getty Images
- Author, Raffi Berg
- Role, BBC News
- Published
Alakoso ifẹsunkanni ti ile-ẹjọ ẹsun ọdaran agbaye, International Criminal Court, Karim Khan ti kọ iwe ẹsun lati gba aṣẹ lori gbigbe awọn alakoso ijọba ilẹ Israel, Benjamin Netanyahu ati ti Hamas fun Gaza, Yahya Sinwar lori ẹsun iwa ọdaran.
Karim Khan sọ pe oriṣiriṣi idi to fi ẹsẹ mulẹ lati gbagbọ pe awọn ọkunrin mejeeji yii ni wọn ṣokunfa iwa ọdaran ogun to lodi si ẹtọ ọmọniyan latigba ti ikọlu Hamas si Israel ti bẹrẹ lọjọ keje, oṣu kẹwaa, ọdun to kọja titi di asiko yii.
Minisita fọrọ eto aabo ilẹ Israel, Yoav Gallant ati olori eto oṣelu ilẹ Hamas, Ismail Haniyeh, to fi mọ adari ikọ ologun, Mohammed Deif, ni wọn n wa lati fi kele ofin gbe.
ICC, ti wọn fikalẹ si The Hague, ni wọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii ati ofintoto lori igbesẹ Israel nipa bi wọn ṣe jẹ gaba lori ikọ agbebọn lati bi ọdun mẹta sẹyin - ati ti awọn Hamas naa to n ṣẹlẹ lọwọlọwọ.
Ọgbẹni Netanyahu laipẹ yii pe awọn agbaagba alẹnulọrọ nilẹ Israel lati darapọ mọ ICC lati wa awọn ti wọn n wa yii.
Awon onidajọ ICC ni yoo wa pinnu boya awọn ẹri ti wọn gba naa to ohun ti wọn le fi tọwọ bọ iwe aṣẹ lati gbe awọn eeyan naa - ohun ti wọn ni yoo to ọsẹ tabi oṣu diẹ ko to jade.
Ọgbẹni Khan fi ẹsun kan awọn alakoso ilẹ Hamas wi pe wọn huwa ọdaran to pọ, awọn bii iwa iparun, iṣekupani, kiko awọn eeyan si ahamọ, ifipabanilopọ ati iwa ipa lori ibalopọ, to fi mọ ifiyajẹni.
"Awọn iwa ọdaran to lodi si ẹtọ ọmọniyan wa lara ikọlu atigbadegba to lodi si pipọ awọn ara Israel si Hamas ati awọn ikọ to n lo eroja ogun," eyi lo wa ninu atẹjade naa.
"Lara awọn iwa ọdaran yii, ninu awọn agbeyẹwo wa, lo ṣi n tẹsiwaju titi di oni."
O ni Hamas ti da ọpọlọpọ ọgbẹ si awọn eeyan lara, pẹlu iwa ipa ati ọdaju wọn

Oríṣun àwòrán, Reuters
Bakan naa lo tun fi kun ọrọ rẹ pe Olootu ijọba Israel, Benjamin Netanyahu ati minisita rẹ fọrọ eto aabo, Yoav Gallant ni wọn jẹ afurasi iwa ọdaran, eyi ti wọn fi n fiya jẹ awọn araalu nitori ogun wọn.
Bẹẹ lo ni wọn tun n paayan, ati pe wọn tun mọ-ọn-mọ n ṣe ikọlu si awọn araalu, bẹẹ ni wọn n gbe wọn si ahamọ.
Ọgbẹni Khan sọ pe ọfiisi rẹ ni awọn ẹri to sọ pe Israel ti mọ-ọn-mọ dena awọn ohun to le mu igbe aye irọrun ba awọn araalu ti wọn wa kaakiri Gaza, lai bikita lori eto ilera wọn.
Ni ti Israel, o sọ pe wọn ni ẹtọ lati daabo bo ara wọn lai kii ṣe pe wọn mọ-ọn-mọ fa iku, ifiyajẹni nla, ati ọgbẹ si ara tabi ilera awọn araalu to n pọ sii, eyi to sọ pe lara iwa ọdaran naa ni.
Benny Gantz to jẹ minisita fun igbimọ ogun ilẹ Israel - eyi to jẹ ẹgbẹ oṣelu alatako ti Ọgbẹni - ti sọ pe ohun lodi si ipinu igbimọ awọn olufẹsunkan.


























