Ọwọ́ ọlọ́pàá tẹ akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́jọ lórí ẹ̀sùn pé wọ́n dáná sun ilé ẹkọ̀ tí akẹgbẹ́ wọn 16 ti kú

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ileeṣẹ ọlọpaa orilẹede Kenya ti sọ pe oun ti fi ṣikun ofin mu akẹkọọ mẹjọ ti wọn fura si pe wọn lọwọ ninu ina to ṣẹyọ nile ẹkọ kan, eyii to mu ẹmi akẹkọọ mẹrindinlogun lọ.
Afẹmọju Ọjọbọ ni ina ọhun ṣadede ṣẹyọ nile ẹkọ awọn obinrin Utumishi Girls Academy to wa ni Gilgil to jẹ kilomita 120 siluu Nairobi, to n ṣe olu ilu orilẹede naa.
Lẹyin ti agbofinro fi ọrọ wa awọn olukọ ati ọpọ akẹkọọ lẹnuwo, ti wọn si wo ẹrọ CCTV to wa nibẹ ni wọn fidi rẹ mulẹ pe akẹkọọ mẹjọ kan lo pilẹ iṣẹlẹ naa ti wọn si sọ ina sile ẹkọ ọhun.
Wọn ni iwadii ṣi n lọ lọwọ lati mọ pato bi ina naa ṣe bẹrẹ.
Ọlọpaa ni wọn ti awọn akẹkọọ naa mọlẹ lati fi ọrọ wa wọn lẹnu wo lẹyin ti wọn kọkọ tọpinpin wọn lọ sile ti wọn n gbe ti wọn si ko wọn pada wa sile ẹkọ naa fun iwadii.
Awọn akẹkọọ mẹjọ naa wa lara awọn akẹkọọ ọgbọn ti wọn kọkọ foju si lara ti wọn si ke si pe ki wọn pada wa sile ẹkọ naa fun ifọrọwerọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Minisita eto ẹkọ, Julius Ogamba sọ pe iwadii fi han pe awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa ṣe awọn ohun to tako eto idaabobo awọn akẹkọọ naa.
Lara rẹ ni bi awọn akẹkọọ to n wa ninu yara kan ṣe pọ ju iye awọn to yẹ ko wa nibẹ lọ ati bi wọn ṣe ti ilẹkun ti wọn le maa gba jade lasiko pajawiri.
Minisita ọhun ti wa tu igbimọ to n ṣakoso ile ẹkọ naa ka, o si ti paṣẹ ki wọn fiya to tọ jẹ olori ile ẹkọ ọhun.
O fi kun pe iya to tọ yoo tun tọ si ẹnikẹni mii ti iwadii ba fi han pe o kuna lati ṣe ohun to yẹ nibẹ ṣaaju iṣẹlẹ ọhun.
Iná ṣẹ́yọ nílé ẹ̀kọ́, pa akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìndìnlógún, 79 farapa

Oríṣun àwòrán, Reuters
Ko din ni akẹkọọ mẹrindinlogun, (16) ti wọn ti ṣe alaisi bayii latari ina kan to ṣẹyọ nile ẹkọ Utumishi Girls ti awọn ọmọbinrin n gbe (Boaridng school) ni Gilgil, orilẹede Kenya.
Yatọ si awon to di oloogbe, akẹkọọ mọkandilọgọrin (79) ni wọn tun farapa ti wọn si gbe lọ sile iwosan.
Akọwe igbimọ to n ri si eto ẹkọ ni Kenya, Julius Ogamba, fidi iṣẹlẹ ati onka naa mulẹ fun BBC.
Ile ẹkọ awọn obinrin Utumishi Girls Academy, Gilgil, lagbegbe Nakuru, ko ju maili mẹtadinlọgọrin lọ si olu ilu Kenya ti I ṣe Nairobi.
Ki lo fa ina ajonirun yii?

Oríṣun àwòrán, Robert Maina
Gẹgẹ bi Akọwe igbimọ to n ri si eto ẹkọ ni Kenya, Julius Ogamba ṣe ṣalaye ohun to fa ina naa, o sọ pe:
"Ni nnkan bii aago kan oru ku iṣẹju mẹẹẹdogun ni ina ọhun ṣẹyọ ni àjà keji ninu awọn ile tawọn akẹkọọ n sun. Gbogbo ibẹ lo si jo run.
"Ikọ alaabo gbiyanju lati debẹ ni nnkan bii aago mẹta oru, amọ nnkan ti bajẹ nigba ti wọn yoo fi de."
Ogamba fi kun un pe ile ẹkọ naa yoo gba awọn obi ati alagbatọ laye lati maa mu awọn ọmọ wọn lọ sile bayii, bawọn alaṣẹ ṣe n ṣewadii ohun to fa ina naa.
Apapọ akẹkọọ ti won ni nile ẹkọ naa jẹ 815 bi Ogamba ṣe ṣalaye.
O ni awọn 808 lo wa nile ẹkọ lasiko ti iṣẹlẹ aburu naa waye, nigba ti awọn meje wa nile awọn obi wọn.
"Awọn mẹrindinlogun lo di oloogbe, a maa gbe orukọ wọn jade.
"Awọn oluwadii yoo tọpinpin iṣẹlẹ yii."
Ogamba lo sọ bẹẹ.
O fi kun un pe akẹkọọ mọkanlelaadọrin (71) ni wọn ti da silẹ nile iwosan, lẹyin ti wọn gba itọju tan.
Meje ni awọn to ṣi wa nidubulẹ lọsibitu, ti wọn n gba itọju bi Akọwe to n ri si eto ẹkọ naa ṣe sọ.
Gẹgẹ bi awọn alaṣẹ ṣe wi, iwadii ohun to fa ina naa ti bẹrẹ, bẹẹ ni igbesẹ n lọ lati mọ awọn to kan, ati bi wọn yoo ṣe ran ẹbi wọn lọwọ.
"Wọn ṣi n wa awọn akẹkọọ kan to fi ibẹru sa jade lasiko ina naa"

Ọga ọlọpaa Kenya, Masoud Mwinyi, ninu ọrọ tirẹ, ṣalaye pe awọn akẹkọọ kan sa wọ awọn agbegbe to wa nitosi lasiko ti ina ọhun ṣẹyọ.
O ni awọn alaṣẹ ṣi n wa wọn.
"Ba a ṣe n sọrọ yii, awọn oṣiṣẹ wa n fọ gbogbo agbegbe to wa nitosi ka ni, nitori awon akẹkọọ kan fi ibẹru sa jade loru naa."
Mwinyi sọ pe wọn ti ta okun di ile ẹkọ yii pa, awọn obi nikan ni aaye wa fun lati wọle sinu ọgba.
Ọkan lara awọn eeyan ti ọmọ wọn farapa, Wambui Nderitu, ṣalaye pe ibatan oun fi ẹsẹ kan, nigba to bẹ silẹ lati ori oke ile naa ki ina ma baa jo o.
O ni ṣugbọn ko ku.
Ina ṣiṣẹyọ nile ẹkọ tawọn akẹkọọ n gbe wọpọ ni Kenya
Eyi kọ ni igba akọkọ ti ina yoo ṣẹyọ nile ẹkọ tawọn akẹkọọ n gbe ni Kenya.
Akọsilẹ fi han pe awọn iru rẹ to ṣẹlẹ lọdun diẹ sẹyin mu ẹmi lọ pẹlu.
Pupọ iṣẹlẹ naa waye latari ibinusọ ina sile, nigba ti awọn akẹkọọ ba n beere fun ohun ti wọn ro pe o jẹ ẹtọ awon nipa ibi ti wọn n gbe ati ọwọ ti awọn alaṣẹ ile ẹkọ naa fi n mu wọn.
Apọju ero ninu awọn yara miran ti awon akẹkọọ n sun, ti wọn ko si tẹle ofin to de aabo, maa n fa ina nigba mi-in nile ẹkọ.
Awon oju opo pajawiri ti eeyan le sare gba kọja lasiko ewu pẹlu awọn ferese le ti wa ni titipa, eyi to maa n fa iku ọpọ ọmọ nigba mi-in lorilẹede naa.

























