Òṣèré tíátà míì jáde láyé

Pat Ugwu

Oríṣun àwòrán, Pat Ugwu/Instagram

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Òṣèré tíátà Nàìjíríà, Ugwu Patience Ogechi, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Pat Ugwu ti dágbére fáyé.

Ní ọjọ́ Karùn-ún, oṣù Kejì, ọdún 2025 ni òṣèré mìíràn, Emeka Okoye fi ìkéde náà sórí ìkànnì Instagram rẹ̀.

Okoye ní ó ṣeni láàánú pé òun àti òṣèré náà kò ní lè ṣiṣẹ́ papọ̀ mọ́.

Ó tún kọminú lórí bí ikú ṣe ń já àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ gbà lẹ́nu ọjọ́ mẹ́ta yìí, bí ó ṣe gbàdúrà pé kí Ọlọ́run dá àwọn akẹgbẹ́ òun sí pàápàá àwọn tí àwọn súnmọ́ ra.

"Bí àwọn ṣe ń dágbére fáyé yìí ń kọmí lọminú.

A kò lè fìdí ohun tó ṣokùnfà ikú òṣèré náà múlẹ̀ lásìkò tí à ń kó ìròyìn yìí jọ.

Àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ ti ń ṣelédè lẹ́yìn rẹ̀ lórí ayélujára.

Ẹni ọdún márùndínlógójì ni Pat Ugwu kó tó jáde láyé.