Ọwọ ìkọ̀ Amotekun tẹ àwọn adigunjálè lásìkò tí wọ́n ń ṣọṣẹ̀ l'Ondo

Aworan awọn Adigunjale

Oríṣun àwòrán, Ondo Amotekun

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Ọjọ gbogbo ni t'ole ọjọ kan ni t'olohun bẹẹ gẹẹ lori fun James Amos ẹni ọgbọn ọdun ati Moses Punsak, ẹni ọdun mọkanlelogun lẹyin ti ọwọ tẹ wọn lasiko idigunjale lagbegbe High School n'ilu Akure.

Ọga Agba fun ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo Akogun Adetunji Adeleye lasiko to n foju awọn ọdaran naa ati awọn meje miran han salaye rẹ pe ọwọ tẹ awọn afunrasi mejeeji lasiko ti wọn n gbiyanju lati pa ọlọde to n sọ agbegbe naa.

Akogun Adeleye salaye rẹ pe wọn gba ibọn ati awọn ohun elo miran lọwọ awọn mejeeji.

Adeleye tun tẹsiwaju sọpe wọn yoo ri daju pe awọn afunrasi yii fẹnu fẹra bi a ẹbẹ, bi o o ṣe seleri pe wọn yoo gbe wọn lọ ile ẹjọ fun idajọ to o peye.

Aworan

Oríṣun àwòrán, Ondo Amotekun

O salaye rẹ pe ọwọ tẹ awọn ọmọ iya meji ti wọn n ji Okada kaakiri igboro Akurẹ. Adeleye sọpe isẹ otelemuye ajọ naa lo jẹ ki ọwọ tẹ awọn afunrasi yii.

Ọkan lara awọn afunrasi naa, eyi to jẹ Ẹ̀gbọ́n sọpe wọn ma n la igi mọ awọn Olokada ti wọn yoo si gbe okada wọn.

Awọn ikọ Amotekun gba okada meji lọwọ awọn afunrasi naa ti Adeleye si seleri pe awọn mejeeji yoo foju wina ofin bakanna.

Akogun Adetunji Adeleye sọpe Ijọba Ipinlẹ Ondo labẹ idari Gomina Lucky Aiyedatiwa ti sagbekale Amotekun Rangers lati le fopin si ija tó n waye laarin awọn agbe ati awọn darandaran.

O salaye rẹ pe igbese yii yoo fopin si bi awọn kọlọrọnsi eda ṣe n wọ igbo ọba ati awọn oko jakejado Ipinlẹ Ondo.

Bẹẹni o salaye pe awọn AMOT RANGERS yii yoo wa lawọn ẹnu ibode Ipinlẹ Ondo lati le fopin si iṣẹlẹ ijinigbe eyi to ti di lemọlemọ nipinlẹ Ondo.

O seleri rẹ pe iṣẹlẹ ijinigbe yoo di afisẹyin ti eegun alare n fi ọ.

Awoarn

Oríṣun àwòrán, Ondo Amotekun