Wo bí o ṣe lè dá ẹni tó ní Ebola mọ̀, àti bí o ṣe lè dènà rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ni bayii ti ijọba Naijiria ti fidi rẹ mulẹ pe arun ebola tun ti rapala wọ Naijiria, ọpọ awọn eeyan lo ti bẹrẹ si n fi erongba wọn lede lori rẹ.
Awọn onimọ sọ pe awọn apẹrẹ arun naa le kọkọ fara jọ iba lasan ko to bẹrẹ si n gbọna mii yọ.
Ajọ NCDC ti kede awọn apẹrẹ ti arun ọhun ṣaba maa n fi lede ati ohun ti awọn araalu le ṣe lati dena rẹ layin kan wọn.
Ọdun 2014 ni ebola kọkọ ṣuyọ ni Naijiria lẹyin ti ọkunrin kan, Patrick Sawyer, balẹ si papakọ ofurufu ilu Eko lati Liberia.
Arun naa ṣekupa eeyan mẹjọ lọdun naa lọhun amọ ijọba tete kapa rẹ ko di ohun to n ran gbogbo ilu.
Arun Ebola buru to bẹẹ to le gbẹmi eeyan laarin ọjọ mẹfa si mẹrindinlogun lẹyin to ba ti n fi apẹrẹ han.
Lara awọn orilẹede Afrika ti Ebola ti n ṣọṣẹ lọwọ yii ni Kenya ati DR Condo, nibi to ti gbẹmi eeyan to le ni irinwo.
Ki wa ni awọn apẹrẹ arun ebola?
Oniruru awọn apẹrẹ ni abola maa n fi han to ba kọlu eeyan.
Gẹgẹ bii atẹjade ajọ NCDC, lara awọn apẹrẹ ebola ni iba, ara rirẹ ju bo ṣe yẹ lọ, iṣan ara riro, ori fifọ, ọfun to n dun eeyan, eebi ati igbọnsẹ gbuuru.
Arun naa tun le mu ki inu maa dun eeyan, ki ifun ati ẹdọforo eeyan si tun kọṣẹ.
Ajọ WHO ni arun naa le wa lagọ ara eeyan laarin ọjọ meji si ọjọ mejilelogun ko to bẹrẹ si n farahan.
Bi o ṣe le dena arun ebola
Lara awọn ọna lati dena arun ebola gẹgẹ bii ajọ NCDC ṣe sọ ni fifọ ọwọ rẹ pẹlu omi ati ọṣẹ loorekoore, paapaa ti o ba gbọnsẹ tan.
Ṣọra fun omi ara ẹni to ni arun naa; lara omi ara bẹẹ ni itọ́, ìtọ̀, ẹjẹ ati igbọnsẹ wọn.
Da ara rẹ lẹkọọ nipa awọn apẹrẹ ebola ki o le mọ bi o ṣe le tete yẹra fun.
Tẹlẹ imọran awọn eleto ilera ti o ba ni nnkan lati ṣe pẹlu ẹni to ni arun naa.
Ṣọra fun fifi ọwọ kan awọn ẹranko to ti ku bii adan.
Yẹra fun pinpin awọn nnkan ti omi ara ẹlomii n kan bii aṣọ, abẹrẹ atawọn nnkan mii.
Ma ṣe itọju ẹni to ni ebola funra rẹ lai kii ṣe onimọ eto ilera tabi lai ni imọ itọju alaarun naa ṣaaju.
Ẹwẹ, ajọ WHO kede awọn abẹrẹ Ervebo ti ileeṣẹ Merck & Co. ṣe, to fi mọ Zabdeno ati Mvabea ti Janssen Pharmaceutica ṣe gẹgẹ bii awọn abẹrẹ ajẹsara rẹ amọ awọn abẹrẹ naa ṣọwọn.
Èèyan kan ní àrùn Ebola ní Nàíjíríà, wọ́n n wá èèyan 44 tó farakínra pẹ̀lú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ilẹ Naijiria ti kede pe ajakalẹ arun Ebola ti wọ orileede naa, pẹlu bi wọn ṣe n wa awọn eeyan ti ko din ni mẹrinlelogoji to ṣee ṣe ki wọn maa gbe arun naa kaakiri.
Ilu Abuja tii ṣe olu-ilu orileede naa ni awọn alakoso ti sọ pe awọn ti ṣawari awọn ẹnikan to ti ni arun naa lara.
Minisita feto ilera nilẹ Naijiria, Ọjọgbọn Muhammed Ali Pate lo fidi iroyin naa mulẹ fawọn akọroyin lọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2026.
Atẹjade ti minisita naa fi lede sọ pe obinrin kan lo ṣẹṣẹ rin irin-ajo de lati orileede Uganda, to si balẹ si ilu Abuja.
O ni kete ti obinrin naa ti de, lo ti lọ si ile iwosan aladani kan ni FCT, nibi to ti n gba itọju, ko too di pe wọn ṣawari arun Ebola naa lara rẹ.
Atẹjade ọhun sọ siwaju pe gbogbo awọn mẹrinlelogoji ti obinrin naa ni ibaṣepọ pẹlu ni wọn ti ṣawari, ti wọn si ti ko gbogbo wọn sabẹ eto ayẹwo, lati dẹkun itankalẹ.
"Obinrin kan to ṣẹṣẹ de si Naijiria pẹlu ọkọ baalu agbaye lati Uganda, ni wọn da duro si ile iwosan aladani kan ni FCT, nibi to ti gba itọju fun ọpọlọpọ ọjọ, ko to di pe wọn ṣawari Ebola lara rẹ," atẹjade ọhun sọ bẹẹ.
Minisita sọi pe obinrin naa ti wa ni yara itọju lori arun naa.
O ni ileeṣẹ feto ilera ni Naijiria ti n ṣiṣẹ papọ pẹlu ajọ to n ri sọrọ idena itankalẹ ajakalẹ arun NCDC, to fi mọ ileeṣẹ eleto ilera ni FCT lati dẹkun itankalẹ arun Ebola naa.
Bakan naa lo sọ pe ijọba ti n ṣiṣẹ lori awọn mẹrinlelogoji ti obinrin naa ni ibaṣepọ pẹlu, ati awọn miran to ṣeeṣe ko tun fara kan, to fi mọ awọn oṣiṣẹ eleto ilera, lati rii pe wọn dẹkun itankalẹ naa.
Siwaju sii lo fidi rẹ mulẹ pe ẹrọ igbalode itọpinpin ti wa nilẹ lati, ati pe ile iwosan ti wọn ti ṣawari arun naa ni yoo ṣe iranwọ fun, lori didena arun ọhun.
Ijọba apapọ wa rọ gbogbo araalu, to fi mọ gbogbo ile iwosan kaakiri Naijiria lati maa wa ojufo, ki wọn si maa kiyesara lori arun naa.
Bẹẹ ni wọn rọ awọn ọmọ Naijiria lati fi ọkan balẹ lasiko ti wọn n dena arun naa, ati pe ki wọn maa fọ ọwọ wọn ni gbogbo igba, ki wọn si jinna si fifi arak an ẹjẹ tabi oogun ara ẹlomiran.
Ijọba sọ pe awọn aisan ti awọn eeyan gbọdọ maa kiyesara rẹ lara awọn eeyan ni iba, ori fifọ, rirẹ eeyan, eebi, ati awọn miran to farapẹ ẹ, paapaa lọdọ awọn to le ti nii lara.
"Ẹnikẹni to ba ni aisan ni lati jinna si awọn eeyan tabi awujọ, ki wọn si ranṣẹ pe awọn oṣiṣẹ eleto ilera fun itọni, ko to di pe wọn lọ si ile iwosan fun itọju," atẹjade naa fi amọran ọhun sita.


























