Obìnrin ẹni ọdún 45 gbé ọkọ rẹ̀ lọ ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn pé kò mú òun lọ Saudi Arabia

Saudi Arabia

Oríṣun àwòrán, Pexels: Mutahir Jamil

Published

Obinrin ẹni ọdun marundinlaadọta kan, Karima Nuhu ti gbe ọkọ rẹ, Musa Falalu, lọ sile ẹjọ kan nipinlẹ Kaduna lori ẹsun pe o kọ lati mu oun lọ si Saudi Arabia.

Karima, to n fi agbegbe Rigasaa niluu Kaduna ṣebugbe sọ fun ile ẹjọ naa pe ọdun mẹrin lawọn fi wa gẹgẹ bii tọkọ-taya, ṣugbọn oṣu meji pere lo fun oun lounjẹ.

O tun sọ fun ile ẹjọ ọhun pe ọkunrin naa lu oun ni jibiti, to si gba gbogbo owo ọwọ oun pata, lẹyin eyii ti o kọ oun silẹ.

O ni “O sọ fun mi pe oun padanu iṣẹ oun gẹgẹ bii awakọ amọ oun riṣẹ mii lorilẹ-ede Saudi Arabia, to si bẹbẹ pe ki n ni suuru pẹlu ileri pe oun yoo mu mi lọ sọhun.”

Saudi Arabia

Oríṣun àwòrán, David Mark from Pixabay

“Lati igba naa wa, emi ni mo n bọ ara mi, koda mo tun n ya owo fun paapaa lara owo ti mo fi pamọ ko le mu mi lọ si irinajo ọhun amọ lẹyin to gba gbogbo nnkan to fẹ gba lọwọ mi tan, o kọ mi silẹ.”

Nigba ti ilẹ ẹjọ bere lọwọ rẹ boya o ni ẹlẹri, o ni “Mi o ni ẹlẹri kankan ayafi Ọlọrun ti yoo ṣedajọ gbogbo wa ni ikẹyin.”

Amọ olujẹjọ ti fesi pe irọ ni gbogbo nnkan ti obinrin naa sọ fun ile ẹjọ.

O fi kun pe oun ti kọ obinrin naa silẹ ṣaaju igbẹjọ ọhun.

Adajọ Anass Khalifa to gbọ ẹjọ naa fidi ikọsilẹ tọkọ-taya ọhun mulẹ, lẹyin naa lo ni oun ko ni gbọ ẹjọ naa mọ ayafi ti olupẹjọ ba mu ẹlẹri wa.

Lẹyin naa lo wọgile si igbẹjọ ọhun.