Wo àwọn Ìpínlẹ̀ tó fún àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba ní ẹ̀bùn ọdún

Oríṣun àwòrán, Others
Ọdun ti yabo fun awọn osisẹ ijọba ni awọn ipinlẹ kan lorilẹede Naijiria lẹyin ti awọn Gomina ipinlẹ naa kede pe awọn yoo san owo oṣu kẹtala fun awọn osisẹ wọn.
Yatọ si pe awọn Gomina kan kede pe awọn yoo san owo oṣu kẹtala bẹẹ ni awọn miiran kede pe awọn yoo fi idaji owo kun owo oṣu awọn osisẹ ijọba.
BBC Yoruba sawari awọn ipinlẹ to ti seleri lati san owo oṣu kẹtala fun awọn osisẹ ijọba nipinlẹ kowa wọn.
Ipinlẹ Oyo

Oríṣun àwòrán, Others
Eyi ki se ajoji si awọn osisẹ ijọba ipinlẹ Oyo nitori lati iṣejọba saa akọkọ ni Gomina Seyi Makinde ti san owo oṣu kẹtala fun awọn osisẹ ijọba nipinLẸ Oyo.
Makinde kede ni bi ayẹyẹ igbaradi ọdun keresimesi to waye ni ile ijọba ipinlẹ Oyo pe oun yoo tun san owo oṣu kẹtala fun awọn osisẹ ipinlẹ Oyo.
“Lati ọdun 2019 ni a ti n se eyi, a dẹ tun fi n da awọn osisẹ ipinlẹ Oyo loju pe a yoo tun ṣe bẹ lọdun yii paapa ki ọdun to pari.”
Ipinlẹ Abia

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ipinlẹ Abia ti seleri lati san owo oṣu kẹtala fun awọn osisẹ gẹgẹ bi ẹbun ọdun fun wọn.
Kọmisana fun eto iroyin nipinlẹ Abia, Obey Kanu lo kede ọrọ naa lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ niluu Umuahia.
O ni Gomina Alex Otti yoo ri daju pe awọn osisẹ ijọba ni anfani si ẹtọ yii.
“Ijọba fẹ mu inu awọn osisẹ dun, a yoo san owo oṣu kejila pẹlu owo oṣu kẹtala.”
Ipinlẹ Edo

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki buwọlu sisan owo oṣu kẹtala fun awọn osisẹ ijọba ni ọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kejila ọdun 2023.
Kọmisana fun eto iroyin nipinlẹ naa, Chris Nehikhara lo kede ọrọ ninu atẹjade to fi sita fun awọn akọroyin pe ipinnu ijọba ipinlẹ Edo ko yipa lati mu ayedẹrun fun awọn osisẹ ijọba,
“Gomina Godwin Obaseki ti buwọlu ọjọ fun sisan owo naa fun awọn osisẹ.
“A yoo san owo oṣu kejila ni ọjọ kọkanla oṣu kejila, ti a yoo sisan owo oṣu kẹtala ni ọjọ kẹtadinlọgbọn ọdun 2023.”
Ipinlẹ Akwa Ibom

Oríṣun àwòrán, Others
Gomina ipinlẹ Akwa Ibom, Pasitọ Umo Eno ti kede pe oun yoo san owo oṣu kẹtala fun awọn osisẹ ijọba nipinlẹ naa.
Ijọba Akwa Ibom kede ọrọ naa lori opo ayelujara X.
“Ijọba ipinlẹ Akwa Ibom labẹ Gomina Umo Eno ti buwọlu sisan owo oṣu kẹtala fun awọn osisẹ ijọba gẹgẹ bi ẹbun ọdun Keresimesi.”
Ipinlẹ Eko

Oríṣun àwòrán, Sanwo Olu
Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko buwọlu afikun ida aadọta afikun owo oṣu fun awọn osisẹ ninu oṣu kejila .
Olori fun osisẹ nipinlẹ Eko, Bode Agoro lo kede ọrọ naa.
Bakan naa Gomina tun buwọlu ohun iranwọ fun awọn osisẹ saaju ki ijọba apapọ to gbe owo oṣu tuntun jade.


























