You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
Àgbékalẹ̀ ètò agbófinró tí kò ní ṣe ojúṣàájú fún ẹnikẹ̀ni ni ìjọba ń fẹ́ – Fagbemi
Adajọ agba ati Minisita fọrọ eto idajọ nilẹ Naijiria, Ọmọọba Lafeet Fagbemi ti sọ pe ko si nnkan meji ti ijọba apapọ n foju sọna fun, bi ko ṣe ilana agbekalẹ eto agbofinro ti ko nii ṣojuṣaaju ẹnikẹni, lai nii ṣe pẹlu ibi ti wọn n gbe, tabi agbegbe ti wọn ti wa.
Fagbemi lo sọrọ naa di mimọ lọjọ Aje, ọsẹ yii nibi ipade awọn akọroyin ti ẹgbẹ alabaṣiṣẹpọ aarẹ lori agbekalẹ ofin eto gbigbe ofin ro, eyii ti olori awọn oṣiṣẹ aarẹ, Fẹmi Gbajabiamila jẹ alaga rẹ.
Adajọ agba sọ pe eto agbekalẹ naa ni lati fi ọkan gbogbo araalu balẹ nipa ilana eto iṣẹ awọn ọlọpaa fun ti idasilẹ ọlọpaa agbegbe ti wọ n foju sọna fun, iyẹn nigba ti wọn ba da a silẹ.
Nigba to n sọrọ, o sọ pe pataki ohun to wa ninu aba naa ni lati rii daju pe eto aabo ẹmi ati dukia araalu fẹsẹ mulẹ daadaa.
Ọmọọba Fagbemi sọ pe o ṣe pakaki lati rii daju pe ọrọ agbekalẹ ọlọpaa ipinlẹ naa ko di ohun elo agbara fawọn oloṣelu lati maa fi dunkooko tabi fiya jẹ awọn eeyan.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe "Pataki ohun to wa ninu aba yii ni lati rii pe aabo wa fun ẹmi ati dukia, bẹẹ si lo tun ṣe pataki wi pe a ko jẹ ki ọlọpaa ipinlẹ di ohun elo agbara fawọn oloṣelu lati fiya jẹni, tabi lati fi ṣe idunkooko.
"Agbekalẹ gbọdọ wa. Ati pe o yẹ ki iwọn abawọle to kere julọ wa lati ṣe idaniloju awujọ le maa ba a lọ, nipa wiwa ati ṣiṣẹ wọn," o sọ bẹẹ.
Ki lawọn anfaani tabi iyatọ laaarin ọlọpaa ipinlẹ ati ọlọpaa apapọ?
Minisita fọrọ eto idajọ tun fi kun ọrọ rẹ pe ni kete ti aba naa ba ti bẹrẹ iṣẹ, agbekalẹ naa yoo lọ ni ibamu pẹlu ilana ti wọn n gba ṣe e lagbaye.
"Bi ẹ ba n lọ lati ọlọpaa apapọ si ti ipinlẹ, o ṣe pataki pe anfaani ti wọn maa jẹ ko nii dinku. Iyatọ ti yoo kan wa nibẹ ni pe ọkan jẹ ti ijọba apapọ, ekeji si jẹ ti ipinlẹ.
"Bi ẹ ba ṣilẹkun silẹm gbogbo oniruuru nnkan ni yoo wọle, eleyii ko sii ni dara to fun agbegbe wa."
O wa fi kun ọrọ rẹ pe nibi ti a ba ti ri ipinlẹ kan, ti ko tii ṣagbekalẹ ileeṣẹ ti yoo maa sabojuto iṣẹ ọlọpaa wọn, ileeṣẹ ọlọpaa ijọba apapọ ni yoo maa tẹsiwaju lati pese aabo nibẹ.
Fagbemi ni, "Ofin ko faramọ ki aaye kan ṣofo, fun idi eyi, awọn apapọ ni yoo jẹ gaba lori agbegbe naa fun itẹsiwaju."
Ki ni ojuṣe igbimọ naa lori idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ?
Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, ẹni to tun jẹ aṣoju ẹgbẹ awọn gomina ninu ẹgbẹ awọn to ṣiṣẹ fu aarẹ lori aba idasilẹ awọn ọlọpaa ipinlẹ sọ pe ojuṣe PWG ni lati ṣagbekalẹ ẹkunrẹrẹ awọn ofin ati ilana fun idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ
Nigba to n sọrọ, o jẹ ko di mimọ pe "Ohun ti a ti ri ni atunṣe iwe ofin, ati pe a tun ti ri atilẹyin ati itẹwọgba awọn araalu to fẹ ko wa si imuṣẹ, pẹlu ireti nla wi pe ni kete ti ile igbimọ aṣofin agba ba ti pari iṣẹ wọn, ohun to kan ni ki awọn ipinlẹ bẹrẹ iṣẹ lati da ilana eto ọlọpaa ti wọn naa silẹ.
"Otitọ to wa nibẹ ni pe ẹgbẹ yii n ṣiṣẹ takuntakun lati rii pe ilana ati eto iṣẹ naa jade lẹkunrẹrẹ, leyi to ni yoo farahan ninu aba naa."