Aráàlú lu ọlọ́pàá méjì pa ní Edo

Oríṣun àwòrán, getty images
Awọn araalu ti lu ọlọpaa meji to n pese abo ‘escort’pa ni ijọba ibilẹ Akoko Edo, nipinlẹ Edo.
Yatọ si awọn ọlọpaa ti araalu lu pa, eeyan meji mii tun farapa yanayana nibi ikọlu naa.
Iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti ọkọ Toyota Hilux ti awọn ọlọpaa naa to n ṣọ ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Edo tẹlẹ, Emmanuel Agbaje, gba alupupu kan.
Iroyin ijamba naa yọri si iku ọkunrin to n wa alupupu ọhun, obinrin kan ati ọmọ obinrin naa.
A gbọ pe eyii lo mu ki awọn ọdọ lati ilu Ikpesi tọpasẹ awọn ọlọpaa ọhun, wọn ṣawari wọn, wọn si lu awọn ọlọpaa naa nilu bara titi ti ẹmi fi bọ lẹnu wọn.
Amọ ṣa, ori ko meji yọ ninu awọn ọlọpaa ọhun lẹyin ti awọn ọmọ ikọ alaabo Edo State Vigilante Network to wa lagbegbe naa doola wọn.
Awọn ọlọpaa ti ori ko yọ naa ti wa nile iwosan bayii, nibi ti wọn ti n gba itọju lọwọ.
Agbẹnusọ ileeṣe ọlọpaa ipinlẹ Edo to fidi iroyin naa mulẹ fun awọn akọroyin, Chidi Nwabuzor sọ pe awọn ọlọpaa ti ọrọ naa kan lo wa lati ẹka Police Mobile Force (PMF) 19, niluu Port Harcourt, nipinlẹ Rivers.
Nwabuzor ṣalaye siwaju si pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa, awọn yoo si jẹ ki araalu mọ esi abajade iwadii wọn ti wọn ba pari rẹ tan.
Kii ṣe igba akọkọ ree ti fakinfa yoo waye laarin ọlọpaa ati araalu nipinlẹ Edo.
Ti ẹ ko ba gbagbe, lẹnu ọjọ mẹta yii lawọn eeyan ilu Benin fẹhonuhan lẹyin ti ọlọpaa ṣeṣi yinbọn lu araalu lasiko ti wọn n le awọn afurasri kan, ti wọn si n fi ibọn halẹ.

























