Ọmọ ọdún 90 ni Ààrẹ Tinubu, Ó sì ń ṣàárẹ̀, ẹ̀rí tó dájú ń bẹ lọ́wọ́ mi - Atiku Abubakar, olùdíje ADC

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Oludije sipo aarẹ lẹgbẹ oṣelu African Democratic Congress, ADC, Alhaji Atiku Abubakar ti ṣalaye idi ti oun fi maa da iranwọ ori epo bẹntiroolu, iyẹn "subsidy" pada bi oun ba wọle ibo sipo aarẹ Naijiria.
Atiku sọ pe oun ti ba ọpọlọpọ awọn onimọ nipa eto ọrọ aje sọrọ, ti wọ si fidi rẹ mulẹ fun oun pe awọn owo to wọle sapo ijọba apapọ lẹyin ti Aarẹ Bola Tinubu yọ iranwọ ori epo naa ni ko ṣe anfaani kankan fun araalu.
O ni dipo ki awọn eeyan jẹ anfaani owo naa, niṣe lo tunbọ sọ ọpọ ọmọ Naijiria sinu iṣẹ ati oṣi.
"Lonii, a wa ninu iṣẹ ati oṣi ju ti atyinwa lọ. Ti ẹ ba wo igbelewọn iṣẹ Naijiria, o ti buru sii. Ijọba ni awọn ti ri ọpọlọpọ owo lẹyin ti wọn yọ iranwo ori epo, amọ ṣe wọn fi owo naa dokoowo si igbayegbadun awọn araalu.
"Eto aabo wa buru sii. Ainiṣẹ n peleke sii, gbese orilẹ ede wa n pọ sii, orilẹ ede wa lara awọn orilẹ ede ti iṣẹ ati oṣi pọ julọ nibẹ, ko si amojuto eto ọrọ to munadoko."
Atiku tẹsiwaju pe bi oun b ani anfaani lati de ipo aarẹ Naijiria, oun maa gbiyanju lati ri pe oun ṣe amulo owo to ba n wọle sapo ijọba bo ṣe yẹ ki gbogbo eeyan paapaa awọn mẹkunnnu jẹ mukundun ijọba awaarawa.
O sọ kii ṣe ọgbọn awọn eeyan ba a le dibo fun oun tabi pe oun wa oju rere awọn eeyan loun ṣe n sọ awọn ọrọ naa bikoṣe bi nnkan ṣe le fun awọn eeyan, to si jẹ pe niṣẹ ni ọpọ n sannani ki wọn to ri jijẹ ati mimu.
O ni oun ti oun yoo ṣe ni lati ri daju pe gbogbo iṣoro ati ilakaka tawọn ọmọ Naijiria n koju ni adinku ba ti oun ko ba tilẹ ri parẹ patapata.
"Ẹtọ mi ni lati dije niye igba to ba wu mi"
Nigba ti BBC beere lọwọ Atiku Abubakar idi to fi n dije sipo aarẹ bi o ṣe jẹ pe ọpọ igba lo ti dije to si fidi rẹmi, Atiku ni ẹtọ oun ni lati dije sipo to ba wu oun labẹ ofin.
O ni ko sigba ti oun wa ipo kan ti oun ri nirọrun nitori naa kii ṣe ohun tuntun fun oun pe oun ko bori ibo ni ẹẹmeji ti oun ti gbegba lati dupo aarẹ ati pe ko si ẹni to lẹtọọ lati maa fi oun ṣe yẹyẹ tabi tabuku oun lori erongba lati dupo aarẹ Naijiria.
O fi kun pe idi ti oun si n tẹmpẹlẹmọ lati dije dupo aarẹ ko ṣẹyin bi nnkan ko ṣe lọ deede ni Naijiria ti oun si ni igbagbọ pe oun maa le wa atunṣe si ti oun ba depo aarẹ.
Bakan naa lo sọ pe oun ni gbogbo amuyẹ lati dupo aarẹ Naijiria, ti oun si jẹ ọmọ Naijiria to le mu ayipada rere ba orilẹ ede yii ni oun ṣe n dije.
O tẹsiwaju pe oun ko ni dije dupo aarẹ Naijiria mọ ti oun ba fidi rẹmi nibi eto idibo ọdun 2027 yii amọ ko tumọ si pe oun ko ni tẹsiwaju lati maa kopa ninu eto oṣelu.
O ni oun yoo maa tẹsiwaju lati pese imọran ati idari wa sọdọ oun logbo oṣelu amọ oun ko nije dupo aarẹ mọ.
"Laaarin ọdun kan ti mo ba dori ipo ni awọn eeyan yoo ti ri ayipada ọtun lẹka eto aabo"
Lori eto aabo to ti di tọrọ fọnka sile ni Naijiria, Atiku ni oun ti oun kọkọ maa mojuto ni gbigba awọn oṣiṣẹ eto aabo paapaa julọ awọn ọlọpaa atawọn Ologun laaarin ọdun kan ti oun ba de ipo.
"Iye ọlọpaa Naijiria ko to 200,000 ti wọn si n ṣọ eeyan to le ni igba miliọnu, Egypt ti awọn eeyan rẹ ko ju ọgọrin miliọnu lọ ni ọlọpaa to le ni miliọnu kan to n ṣọ awọn eeyan."
O fi kun pe oun maa ri daju pe ajọsṣepọ to dan mọran wa laaarin awọn orilẹ ede Africa paapaa awọn ti iwọ oorun Africa lojuna ati le mu eto aabo gbopọn sii.
O ni gbogbo awọn orilẹ ede ti wọn fi ajọ ECOWAS silẹ ni oun maa kọkọ ko pada sibẹ lojuna ati le ri daju pe aabo to peye w ani awọn ẹnubode gbogbo to wọ orilẹ ede Naijiria.

























