Ọ̀mọ̀wé ní wá, àìríṣẹ́ṣe ló mú ká máa gun ọ̀kadà, ẹ yé fòfin dè wá - Accomoran

Published

Ẹgbẹ́ àwọn ọlọ́kadà ráwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba kó gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó ń fi dè wọ́n

Okada ban

Oríṣun àwòrán, @lagospedia

Ẹgbẹ awọn ọlọkada ni Naijiria, ACOMORAN, ti pe ipade lati wa ojutu si ipenija ti awọn ọmọ ẹgbẹ rẹ n dojukọ.

Paapaa nitori bi awọn ijọba ipinlẹ ṣe n fofin de ọkada gigun.

Wọn ni ijọba ko kan le dede maa fofin de awọn lai yanju awọn iṣoro to wa nilẹ ṣaaju.

Aarẹ ẹgbẹ naa, Shamshudeen Apelogun sọ pe nnkan ti n nira fun awọn ọlọkada nitori bi ijọba ṣe n fofin de awọn ni Naijiria.

Wọn gbẹsẹle ọkada wa ti a ya owo ra - Accomoran

Apelogun sọ pe ohun to dun oun ju ninu ọrọ naa ni bi ijọba ṣe n gbẹsẹle ọkada ti awọn ti n ya owo ra, ti ijọba si n ba ọkada naa jẹ.

O sọ pe igbesẹ ijọba naa ti ṣe ipalara fun ọpọ awọn ọlọkada, paapaa awọn to n fi ọkada jẹun nitori pe wọn kawe, ti wọn ko si ri iṣẹ ṣe.

O ni “Idi ree ti a ṣe n bẹ ijọba lati gba ọpọ ero siṣẹ.”

“Kaka ki wọn maa fofin de ọkada, ni ṣe lo yẹ ki wọn wa ọna abayọ, ki ijọba si fọwọsowọpọ pẹlu wa lati yanju eto eto abo to mẹhẹ.”

Lẹyin naa lo bẹ awọn araalu lati to maa gun ọkada ati kẹkẹ maruwa lati ba wọn da si ọrọ naa ki ijọba le yi ipinnu rẹ pada.

Eredi ti ijọba ṣe  fofin ko ju eto abo to mẹhẹ lọ.

Awọn ipinlẹ to ti fofin de ọkada

Lara awọn ipinlẹ to ti fofin de ọkada gigun ni ipinlẹ Eko, Kaduna, Kano, Enugu, Rivers.

Ipinlẹ Ondo naa ti sọ pe oun ko fẹ ri ọkada kankan laarin ilu lati aago mẹfa irọlẹ si mẹfa idaji amọ pupọ awọn ọlọkada naa ni ko tẹle aṣẹ ọhun.

Aarẹ ACOMORAN, Shamshudeen Apelogun ni ti ijọba ba tẹsiwaju lati maa fofin de ọkada, wọn yoo sọ ogoji miliọnu eeyan to n fi iṣẹ ọkada jẹun sinu iṣẹ ati oṣi.