Ilé ẹjọ́ dá adarí ilé aṣòfin ìpínlẹ̀ Eko tẹ́lẹ̀ Ikuforiji láre lórí ẹ̀sùn jíjí N338.8m lọ sóké òkun

Oríṣun àwòrán, RT. Hon. Adeyemi Sabit Ikuforiji/Facebook
Ile ẹjọ giga ijọba apapọ to wa niluu Eko ti dajọ wi pe adari ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko tẹlẹ, Adeyemi Ikuforiji o jẹbi ẹsun jiji N338.8m ko lọ soke okun ti ajọ EFCC fi kan an.
Ile ẹjọ da Ikuforiji silẹ pẹlu amugbalẹgbẹ rẹ tẹlẹ, Oyebode Atoyebi.
Adajọ Mohammed Liman sọ ninu idajọ rẹ wi pe ajọ EFCC to n gbogun iwa ibajẹ ni Naijiria kuna lati fidi ẹsun ti wọn fi kan an mulẹ daadaa.
Ọjọ kinni oṣu Kẹta ọdun 2012 lawọn olujẹjọ naa kọkọ farahan nile ẹjọ lori ẹsun onikoko ogun to da lori ṣiṣe owo ilu kumọkumọ.
Ẹsun jiji owo ko lọ soke okun ni ẹsun miran ti wọn tun fi kan awọn olujẹjọ yii.
Ikuforiji ati amugbalẹgbẹ rẹ sọ nigba naa wi pe awọn o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan awọn.
Ni ọjọ kẹtadinlogun oṣu Kẹta ọdun 2021 ni EFCC wi awijare rẹ tan lẹyin to gbe ẹlẹri keji, Ọgbẹni Adewale Olatunji ti i ṣe akọwe ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Eko tẹlẹ wa sile ẹjọ.
Amọ, ile ẹjọ sun igbẹjọ naa siwaju lati fun awọn olujẹjọ lanfani lati sọ tẹnu wọn.
Ohun ti ajọ EFCC sọ ni pe awọn olujẹjọ gba owo to ju iye ti ofin la kalẹ lọ fun wọn lati gba lọ, ati pe wọn ko lo ile ifowopamọ lati gba owo naa jade.
Ajọ EFCC tun fẹsun kawọn olujẹjọ pe wọn gbimọ pọ lati gba owo to to N338.8m jade lati ile aṣofin ipinlẹ Eko lọna aitọ.
EFCC tun sọ pe Ikuforiji lo ipo rẹ lati lu owo ilu ni ponpo.
Ajọ naa sọ pe laarin oṣu Kẹrin ọdun 2010 si oṣu Keje ọdun 2011 lawọn olujẹjọ ṣe aṣemaṣe yii.
Amọ, Adajọ Liman sọ lọjọ Aje nile ẹjọ wi pe ki Ikuforiji ati amugbalẹgbẹ rẹ maa lọ ni alaafia tori EFCC kuna ninu awijare rẹ lati fidi rẹ mulẹ pe lootọ ni wọn jẹbi ẹsun ti o fi kan wọn.


























