Èèyàn bí ogún jóná kú lásìkò tí 'tanker' gbina ní Kogi
Ko din ni ogun eeyan to jona guruguru lasiko ti ọkọ agbepo kan gbina nipinlẹ Kogi.
Iroyin sọ pe ọkọ agbepo naa to gbe bẹtiro, ṣubu lulẹ lori afara odo Maboro nilu Ankpa, nijọba Ankpa, nipinlẹ Kogi, lẹyin ti awakọ naa sọ ijanu ọkọ nitori bureeki to da isẹ silẹ lojiji.
Isẹlẹ naa waye lẹyin ọsẹ diẹ ti awọn adigunjale yabo awọn banki kan nipinlẹ naa, ti wọn si pa awọn araalu.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun awọn akọroyin pe ni nkan bi aago mẹta aabọ ọsan Ọjọru ni ijamba ọkọ naa waye.
Wọn ni pupọ ninu awọn to ku, ni wọn jona kọja dida mọ.
“Bakan naa ni ọkọ tẹ awọn kan pa, ti ẹya ara wọn si fọn kaakiri oju popo.
Oludari ajọ ẹṣọ ojupopo, FRSC, nipinlẹ Kogi, Stephen Dawulung, sọ fun iwe iroyin Daily Trust pe awọn ko tii le sọ iye eeyan to ku.
Ọgbẹni Dawulung sọ pe ọkọ agbepo naa, bọọsi kan ati ọkọ ayọkẹlẹ mẹta, to fi mọ ọkada mẹta, lo kagbako ijamba naa.
Ao maa fi to yin leti bi iroyin naa ba ṣe n lọ.























