Alásè Ghana lulẹ̀ nínú ìdíje GWR fún síse oúnjẹ fún ìgbà pípẹ́

Published

Ajọ to n ṣe akọsilẹ awọn to tayọ julọ lagbaye, Guiness World Record (GWR) ti wọgile igbiyanju alasẹ kan lati orilẹede Ghana lati gba ami ẹyẹ inadida fun igba pipẹ, eyi to gunle.

Ninu oṣu kinni ọdun 2024 ni o da bi pe Failatu Abdul-Razak ti gba ami ẹyẹ naa lẹyin to dana fun wakati mẹtadinlọgbọnlenigba.

Ọkan lara awọn to n ṣe amojuto Arabinrin Abdul-Razak, Kafui Dey lo kede ọrọ naa lọjọ Aiku, ọjọ kẹta oṣu kẹta ọdun 2024 pe gbogbo igbiyanju naa ko ba ilana ti ajọ GWR gba kalẹ mu.

“Atẹjade lati ajọ ni wọn lodi sofin isinmi, eyi to fa ti wọn fi wọgile igbiyanju naa.”

Agbẹnusọ GWR sọ BBC pe pẹlu bi wọn ṣe wọgile igbiyanju Abdul-Razak, wọn si kan sara si fun igbiyanju rẹ lati gba ami ẹyẹ naa.

O fikun pe igbesẹ GWR ko sẹyin bi ikọ Abdul-Razak ṣe lodi sofin ti GWR gba kalẹ lori isinmi.

Igbiyanju Abdul-Razak lati gba ami ẹyẹ GWR fa ọpọ idunu pupọ lorilẹede Ghana.

Oloṣelu, paapa igbakeji Aarẹ Mahamudu Bawumia, awọn eekan gbajugbaja ati ileeṣẹ ologun orilẹede Ghana kede atilẹyin wọn fun Arabinrin Abdul-Razak lasiko to n gbe igbesẹ naa.

Pẹlu bi o ṣe ri ijakulẹ, Alaṣe naa dupẹ pupọ lọwọ awọn alatilẹyin rẹ fun bi wọn ṣe ti lẹyin lasiko to n dana.

Bẹẹ ba gbagbe, ọdun to kọja ni ọmọ orilẹede Naijiria, Hilda Baci gba ami ẹyẹ pe o dana fun ọpọlọpọ wakati ni gbogbo agbaye

Hilda Baci ṣalaye pe nnkan ti oun n ṣe yii wa lara ala oun to tobi gan to si fi kun un pe o tun jẹ anfani lati gbe itan daadaa nipa ilẹ Afirika ni agbaye nipasẹ ounjẹ ti a n jẹ.

Baci bẹrẹ ounjẹ sise ọlọjọ mẹrin yii ni ọjọ Kọkanla Oṣu Karun ni agbegbe Amore Gardens, Lekki ni ipinlẹ Eko ti gbogbo eniyan si ti n kan saara sii.