Àwọn Iléeṣẹ́ ìtẹ̀wé ṣétan láti wọ́ INEC lọ sílé ẹjọ́

Ajọ awọn atẹwe lorilẹede Naijiria ni awọn ti setan lati wọ ajọ to risi eto idibo orilẹ-ede yii INEC lọ si ile ẹjọlatari bi o ti tẹ ọpọlọpọ ninu awọn eroja rẹ fún ẹtọ idibo ọdun yii ni oke okun.
Ajọ naa ni igbese naa lodi si ofin CIPPON ti ọdun 2007 eyiti ijọba orilẹede yii fowo si.
Nigba ti oun ba awọn akọroyin sọrọ, aarẹ ẹgbẹ CIPPON Olugbemi Malomo ni nitooto ni ajọ INEC gbe awọn isẹ kan fun awọn ọmọ ẹgbẹ CIPPON ṣugbọn ọpọlọpọ awọn iwe ti o yẹ ki awọn tẹe ni wọn gbe lọ si oke okun eyi to lodi si ofin ijọba fọwọ si.
Malomo ni ofin CIPPON ko fayegba ki ajọ INEC gbe iṣẹ iwe titẹ lọ si oke okun ati wi pe ọpọlọpọ awọn ile-iṣẹ itẹwe ti ajọ INEC gbẹ ṣẹ fun ko ni iwe ẹri ati tẹwe ni orilẹ-ede yii.
O ni tẹleri, ajọ INEC ko ni ileeṣẹ itẹwe orilẹede yii to le tẹ iwe fun eto idibo nitori ati gbogun ti iwa aitọ ninu awọn eto idibo ṣugbọn pẹlu lilo ẹrọ igbalode BVAS fun idibo, ko si awijare kankan fun ajọ INEC lati mase gbe iṣẹ fun ajọ CIPPON.

O tẹsiwaju pe o yẹ ki Ijọba wa ọna lati mu idagbasoke baa awọn ile-iṣẹ to wa labẹle bi awọn ile okere ṣe ma n ṣe.
Ẹwẹ alukoro fun oga agba ajọ INEC Rotimi Oyekanmi ni bẹẹ ko ni ọrọ ri.
Nigbati oun sọrọ lori ọrọ ajọ CIPPON Tanko Yunusa ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour ni ko buru ti ajọ INEC baa tẹ awọn iwe eroja eto idibo ọdun 2023 ni oke okun niwọn igbati ofin fayegba.
Tanko ni oseṣee ki awọn eroja ti wọn fi n tẹ iwe idibo lorilẹede yii maa ni aabo to peye.

























