Afurasí akẹ́kọ̀ọ́ fásítì FUNAAB tí wọ́n ló fún ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ ní májèlé jẹ gba ìtúsílẹ̀ ní àhámọ́ ọlọ́pàá

Omolola Odutola
Published

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti ṣalaye bi ọrọ ọmọkunrin akẹkọọ fasiti ẹkọ eto ọgbin ni Abeokuta, FUNAAB, Ọladokun Ayọmide, ti wọn lo fun ọrẹbinrin ẹ, Ugbokwe Mmasichukwu ati ọrẹ iyẹn torukọ tiẹ n jẹ Odumosu Ṣemiloore ni majele jẹ.

Alukoro ọlọpaa Ogun, SP Ọmọlọla Odutọla sọ pe ọjọ Ẹti ọsẹ to kọja ni Ayọmide to wa nipele aṣekagba ni FUNAAB, pe ọrẹbinrin rẹ , Mmasichukwu, lati wa a ba a ṣe ayẹyẹ ọjọọbi, nile rẹ to wa lagbegbe Surulere, Camp, l’Abẹokuta.

O ni nigba ti Mmasichukwu n lọ sibi apeje naa, o mu ọrẹ rẹ, Ṣemiloore, ti wọn jọ jẹ akẹkọọ nile ẹkọ imọ nipa iṣẹ olukọ, Oṣiẹlẹ l’Abẹokuta dani.

O ni nigba ti wọn bẹrẹ faaji ni ọlọjọbi fun wọn ni akara oyinbo onimajele naa jẹ pẹlu ọti ati kinni kan ti wọn gbagbọ pe ohun naa le ṣe jamba fun ara.

Odutọla ni lẹsẹkẹsẹ tawọn ọmọbinrin naa jẹ awọn nnkan yii ni wọn daku lọ gbari ti wọn ko si mọ ibi ti wọn wa mọ.

O fi kun un pe bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to mọ idi ti afurasi ọhun ṣe fun awọn ọmọbinrin naa ni majele jẹ, wọn lo ti ni erokero naa ninu tẹlẹ.

Nigba to n ṣalaye ibi ti iṣẹlẹ naa de duro fun BBC Yoruba l’Ọjọru ọsẹ yii, SP Odutọla sọ pe ile iwosan ni awọn ọmọbinrin meji naa balẹ si lẹyin ti wọn jẹ majele naa.

Odutola sọ pe ni bayii ara wọn ti ya, wọn si ti pada sọdọ awọn obi wọn.

Odutola ṣalaye pe Ayomide ti kuro ni ahamọ ọlọpaa bayii lẹyin tawọn idile rẹ ati idile ọrẹbinrin rẹ ti jọ sọrọ pọ.

Bakan naa ni alukoro ọlọpaa sọ pe awọn mọlẹbi ti da si ọrọ naa, igun mejeeji si ti jọ sọ asọyepọ lori rẹ.