Ikọ̀ Portugal fi Super Eagles panu níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ olọ́rẹ̀ẹ́ sí ọ̀rẹ́

Aworan Iwobi ati Ronaldo

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Published

Ikọ̀ Portugal fi Super Eagles panu níbi ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ olọ́rẹ̀ẹ́ sí ọ̀rẹ́ tó wáyé ní pápá ìṣeré José Alvalade nílùú Lisbon lálẹ́ yìí.

Ami ayo merin si odo ni ikọ agbabọọlu Portugal fun ti Super Eagles Naijiria.

Idije ife ẹyẹ agbaye yoo bẹ\rẹ ni orilẹ-ede Qatar.

Naijiria ko pegede lati kopa nibe rara.

Nàìjíríà yóò kojú Portugal ní ifẹsẹ̀wọnsẹ̀ ọlọ́rẹ́sọ́rẹ́: Èyí lohun tó yẹ kí o mọ̀

Ẹgbẹ agbabọlu Super Eagles Naijiria yoo koju Portugal fun ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ  kan lọjọbọ.

Ifẹsẹwọnsẹ yii n waye lọjọ diẹ si ibẹrẹ idije ife ẹyẹ agbaye Qatar 2022.

Orilẹede Naijiria ko ni kopa ni idije ife ẹyẹ agbaye FIFA yii ṣugbọn Portugal yoo kopa, wọn yoo si ma koju Ghana, Uruguay ati South Korea ni ipin H.

Ifẹsẹwọnsẹ yii yoo waye lẹyin ifọrọwerọ Christiano Ronaldo pẹlu Piers Morgan to gbalẹkan bayii nibi to ti bu ẹnu atẹ lu awọn alaṣẹ Manchester United pe wọn da oun.

Awọn ohun to yẹ ki o mọ niyi nipa ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ yii.

Awọn agbaboolu Super Eagles n gbaradi

Oríṣun àwòrán, Super Eagles/ twitter

Nigba wo ni ifẹsẹ̀wọnsẹ Portugal ati Naijiria yoo waye?

Ifẹsẹwọnsẹ naa yoo waye ni Ọjọbọ, ọjọ kẹtadinlogun oṣu kọkanla ni nnkan bii agogo mẹjọ ku iṣẹju marundinlogun aṣalẹ.

Orukọ awọn agbabọọlu Naijiria to n kopa

Awọn agbaboolu Super eagles n gbaradi

Oríṣun àwòrán, Super eagles/twitter

Agbabọọlu mẹtalelogun ni Naijiria pe fun ifẹsẹwọnsẹ naa.

Amọṣa, akọnimọọgba Super Eagles, Jose Peseiro ti fi Cyriel Dessers rọpo Victor Osimhen, ti Chidozie Awaziem fun Olisah Ndah nitori pe wọn ṣeṣe.

 

Aṣọle: Maduka Okoye, Francis Uzoho, Adebayo Adeleye

Agba ọwọ ẹyin (Defenders) : William Ekong, Olisa Ndah, Calvin Bassey, Kevin Akpoguma, Chidiebube Duru, Tyronne Ebuehi, Bruno Onyemaechi, Bright Osayi Samuel

Agba ọwọ aarin (Midfielders) : Joseph Ayodele-Aribo, Alex Iwobi, Wilfred Ndidi, Frank Onyeka, Oghenekaro Etebo

Atamatase (Forward) : Moses Simon, Samuel Chukwueze, Ademola Lookman, Terem Moffi, Paul Onuachu and Emmanuel Dennis

Orukọ awọn agbabọọlu fun Portugal niyii:

Awọn agbaboolu Portugal n gbaradi

Oríṣun àwòrán, Portugal/twitter

Aṣọle: Diogo Costa, Jose Sa, Rui Patricio

Agba ọwọ ẹyin (Defenders) : Diogo Dalot, Joao Cancelo, Danilo Pereira, Pepe, Ruben Dias, Antonio Silva, Nuno Mendes, Raphael Guerreiro

Agba ọwọ aarin (Midfielders) : Joao Palhinha, Ruben Neves, Bernardo Silva, Bruno Fernandes, Joao Mario, Matheus Nunes, Otavio Monteiro, Vitinha, William Carvalho

Atamatase (Forward) : Andre Silva, Cristiano Ronaldo, Goncalo Ramos, Joao Felix, Rafael Leao, Ricardo Horta