Ilé ìgbìmọ̀ Aṣojú-ṣòfin buwọ́lu àbádòfin fún ìdásílẹ̀ ọlọ̀pàá ìpínlẹ̀ lórílẹ̀èdè Nàìjíríà

Apa kan awọn aṣofin nile igbimọ

Oríṣun àwòrán, Nigerian Senate

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Aba lati ni ọlọpaa ipinlẹ lorilẹede Naijiria, eyi ti awọn aṣofin ti wa lori rẹ fun igba pipẹ, ni ile igbimọ aṣoju-ṣofin ti buwọlu bayii.

Eyi waye l'Ọjọbọ, ọjọ kẹtalelogun oṣu Keje ọdun 2026 yii.

Lasiko ijokoo ipade awọn aṣofin naa ni wọn fẹnuko le aba naa lori, leyin ti wọn fagile atunṣe tẹlẹ ti wọn ṣe lori idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ ọhun, ti wọn si gba eyi wọle.

Ki ni ọlọpaa ipinlẹ da le lori ?

Igbesẹ yii ni yoo fun awọn ipinlẹ Naijiria lanfaani lati ni ọlọpaa ti yoo jẹ ti agbegbe wọn, ti wọn yoo si da duro yatọ si ti ijọba apapọ.

Aba ti wọn buwọlu yii ni afojusun wa fun pe yoo mu iṣẹ ọlọpaa rọrun lẹsẹkuku, nibi ti awọn ọmọ ipinlẹ to mọ tinutẹyin agbegbe wọn yoo ti le ṣiṣẹ agbofinro.

Aabo agbegbe ni ireti tun wa pe yoo dara si i bi ọlọpaa ipinlẹ ba wa.

Bi ile igbimọ aṣoju ṣe tun buwọ lu u bayii lẹyin ti ile igbimọ aṣofin agba ti buwọlu u, n tọka si pe igbesẹ ọlọpaa ipinlẹ ti n farahan pe yoo ṣee ṣe.

Wọn yoo gbe mejeeji lọ si ẹka ofin to kan, ko too de ọdọ aarẹ fun ibuwọlu ti yoo sọ ọ di ofin.

Ẹ o ranti pe o pẹ ti awọn alẹnulọrọ ati araalu ti n pe fun idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ,ko too di pe ẹkọ n fojuu mimu han lori rẹ bayii.

Ki lo wa ninu aba idasilẹ ọlọpaa ipinlẹ?

Labẹ aba tuntun yii, ọlọpaa ijọba apapọ ko ni i yọju si iṣẹ awọn tipinlẹ, afi awọn eyi to ba le gidi ti apa ipinlẹ ko ka.

Gomina ipinlẹ tọrọ kan ni yoo pe ọlọpaa apapọ ki wọn too le dide iranwọ fun wọn.

Bakan naa ni aba tuntun yii n pe fun ayipada nipa bi wọn ṣe n yan ọlọpaa sipo.

Ninu aba naa ni wọn ti ni ki Aarẹ maa yan ọga agba ọlọpaa pata, pẹlu imọran latọdọ igbimọ apapọ ọlọpaa Naijiria, ṣugbọn aba naa sọ pe gomina ni yoo maa yan kọmiṣanna ọlọpaa fun ipinlẹ rẹ.

Yoo maa yan kọmiṣanna naa lara awọn ọlọpaa to n ṣiṣẹ fun ilu rẹ, ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa ni yoo si pada buwọlu u.

Ninu aba yii, gomina lagbara lati paṣẹ fun kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ rẹ lori ọrọ aabo ilu.

Ṣugbọn bi kọmiṣanna naa ba ri i pe aṣẹ ọhun ko ba ofin mu, tabi ti lodi si ofin iṣẹ ọlọpaa, wọn le dari ọrọ naa si ọdọ igbimọ ọlọpaa ijọba apapọ, ohun ti awọn iyẹn ba si sọ ni abẹ ge.