You’re viewing a text-only version of this website that uses less data. View the main version of the website including all images and videos.
PDP ní Tinubu kò lẹ́tọ̀ láti díje fún ipò ààrẹ Nàìjíríà lọ́dún 2023
- Author, Alebiosu Olubayode
- Role, Broadcast Journalist
- Reporting from, Lagos
- Published
Ẹgbẹ oṣelu Peoples Democratic party lorilẹede Naijiria ti ke si oludije fun ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress, APC, Bọla Tinubu pe ko jawọ ninu idije fun ipo aarẹ Naijiria to n rawọle.
PDP ni ko si idi fun Tinubu lati dije fun ipo aarẹ mọ lẹyin ti iroyin jade pe ile ẹjọ kan lorilẹede Amẹrika ti gbẹsẹ le owo kan ti wọn ni o wa ninu aṣuwọn ifowopamọsi banki kan to jẹ orukọ rẹ.
PDP sọ ọ ninu atẹjade kan eyi ti alukoro rẹ, Debo Ologunagba fọwọsi pe bi o ba jẹ pe ootọ ni ohun ti ile ẹjọ naa to fikalẹ si agbegbe Illinois lorilẹede Amẹrika gbe kalẹ, a jẹ wi pe Tinubu ko lee kopa ninu idibo sibo aarẹ lọdun 2023.
“Abala kẹtadinlogoje iwe ofin Naijiria ti ọdun 1999 sọ pe: 1.) eniyan ko ni lee dije fun ipo aarẹ bi o ba:
“Wa labẹ idalẹbi idajọ iku ni ile ẹjọ kankan lorilẹede Naijiria tabi ti ILE ẸJỌ KANKAN ba ti daa lẹjọ ẹwọn tabi owo itanran fun eyikeyi ẹsun jibiti, (labẹ orukọ yoowu ti wọn le pe e) tabi fun ẹsun miran.”
PDP ni gbigbẹsẹ le dukia ẹnikẹni nile ẹjọ tumọ si pe irufẹ ẹni bẹẹ ti jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an naa.
Bawo lọrọ gbigbẹsẹ le aṣuwọn banki ni ile ẹjọ Amẹrika ṣe jẹ pẹlu Bọla Tinubu?
Iroyin jade laipẹ yii nipa ọrọ ile ẹjọ kan lorilẹede Amẹrika to kan oludije ẹgbẹ oṣelu APC, Bọla Tinubu lọdun 1993 eleyi ti awọn alatako rẹ n tẹnumọ kaakiri bayii.
Awọn igun agba oṣelu aṣiwaju ẹgbẹ oṣelu APC naa si ti n wi ti ẹnu wọn lati bu omi pa ina iroyin naa ti wọn ni ko ṣẹṣẹ maa waye lati igba ti Tinubu ti bẹrẹ irinajo oṣelu rẹ lọpọ ọdun sẹyin.
Igbimọ ipolongo fun Bọla Tinubu ti sọ pe ọpọ igba lawọn ololufẹ Tinubu pẹlu igbimọ ipolongo rẹ ti bọ sita lati sọ pe ko si ohun to jọ iroyin yii.
Amofinagba Festus Keyamo, to jẹ Agbẹnusọ fun igbimọ ipolongo Bọla Tinubu ti sọ pe ki ẹnikẹni maṣe fa orukọ oludije ẹgbẹ oṣelu APC naa sinu ọrọ ipẹjọ ti wọn n sọ lorilẹede Amẹrika ọhun.
“Ko si bi idalẹbi ṣe le wa niwọn igba ti Aṣiwaju kii ṣe olujẹjọ ninu ẹjọ naa”
Festus Keyamọ sọrọ yii ninu ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ iroyin abẹle kan
“Mo n tuu sọ fun igba igba pe Aṣiwaju ko si ninu awọn ti wọn pe lẹjọ ninu ipẹjọ naa”
Atẹjade ti ko mu ọpọlọ dani rara niyi – Amofin agba Festus Keyamo
Nigba to n fesi si atẹjade ti ẹgbẹ oṣelu PDP fi sita yii, agbẹnusọ fun ikọ ipolongo ibo fun Bọla Tinubu, Amofin agba Festus Keyamo sọ pe atẹjade naa ko mu ọgbọn dani rara.
O ni ki lo de ti ẹgbẹ oṣelu PDP ko gba ile ẹjọ lọ ti wọn ba mọ pe lootọ ni ọrọ gbogbo ti wọn n gbe jade ninu atẹjade yii da awọn loju.
“Ṣe ipade pẹlu awọn akọroyin tun ni ile ẹjọ bayii ni? Ọna ti di mọ ẹgbẹ oṣelu PDP, ni wọn fi n fẹ gba ọna eru ibanilorukọjẹ ati lilo beba inuwọ lati orilẹede Amẹrika.”
O ni ẹgbẹ oṣelu alatako ti wa sọ ori ayelujara di ile ẹjọ.
Keyamo ni ki wọn gba ile ẹjọ lọ bi wọn ba ni iwe ẹri to daju ti wọn mọ pe yoo de Tinubu lọna idije fun ipo aarẹ.