'Ilé olórogún kìí rọrùn, kódà kí ọwọ́ ìwọ ìyálé mọ́'

Kàyééfì ńlá ní Ilorin, ọmọ ìyà mẹ́ta kú sínú ọkọ̀
Iṣẹlẹ a gbọ bomi loju kan sẹlẹ niluu Ilorin nigba ti awọn ọmọ kekeke mẹta ti wọn jẹ ọmọ iya kan naa ṣadeedee ku sinu ọkọ.
A gbọ pe iṣẹlẹ naa sẹlẹ ni ile baba awọn ọmọ yii, lagbegbe Sango ni ijọba ibilẹ ila orun Ilorin, tii ṣe olu ilu ipinlẹ Kwara.
Ọkan lara awọn eyan agbegbe naa to ba BBC Yoruba sọrọ Ọgbẹni Ahmed Arikewusọla ṣalaye pe inu ile wọn ni iṣẹlẹ naa ti ṣẹlẹ ni ikan bi ago meji ọsan ọjọ Aiku.
O fikun pe lati igba ti baba awọn ọmọ naa ti fẹ iyawo keji ni alaafia o ti jọba mọ ninu ile tọkọtaya naa.
O tẹsiwaju ninu ọrọ rẹ pe, bo tilẹ jẹ wi pe wọn ti bawọn pari ija naa sugbọn ibaṣepọ wọn ko oda bi ti tẹlẹ.
O ni lana ni isọmọ lorukọ iyawo keji ti ọkunrin naa sẹsẹ fẹ, sugbọn iya lẹnu lo jẹ pe iyale o lọ.
O tẹsiwaju pe, bi ọkọ ṣe lọ ibi isọmọ lorukọ tan, wọn bẹrẹ si ni wa awọn ọmọ naa, lai mọ pe awọn ọmọ mẹtẹẹta ti wọ inu ọkọ Baba wọn ti wọn si ti lẹkun ọkọ mọ ara wọn.


Lẹyin ọpọ wakati ti wọn ti n wa wọn ni iya wọn ri bata wọn ni idi ọkọ to si fi tipatipa si ilẹkun ọkọ ni ibi to ti ri awọn ọmọ naa ti oru ti bo wọn.
Wọn si gbe wọn lọ ile iwosan to wa lẹgbẹ ile wọn, nibi ti dokita ti ni ki wọn mọn gbe wọn lọ ile iwosan nla (UITH) ni ibi ti wọn ti fi idi rẹ mulẹ pe awọn ọmọ naa ti ku.
Ẹwẹ, wọn ti sin oku awọn ọmọ naa bayii.
BBC Yoruba kan si ile ti iṣẹlẹ yii ti waye, amọ, a koba ẹni kankan ni ile naa.
Awọn ara adugbo sọ pe wọn ti mu iya awọn ọmọ naa lọ ọdọ iya rẹ.























