Wọ́n yọ ìmáàmù nípò, wọ́n ló ń fi wáàsí polongo sáà kejì fún Tinubu

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Imaamu kan ti padanu ipo rẹ bayii, lori ẹsun pe o n fi waasi rẹ polongo ibo saa keji fun Aarẹ Bola Tinubu.
Iṣẹlẹ yii waye nipinlẹ Bauchi, Imaamu naa ni wọn pe orukọ rẹ ni Dahiru Abubakar.
Mọṣalaaṣi ti Imaamu ọhun si ti n kirun fun wọn tẹlẹ ki wọn too yọ ọ nipo ni wọn n pe ni Madina.
Ki ni wọn ni Imaamu ṣe gan-an?
Gẹgẹ bi iroyin ṣe ro o, Imaamu Dahiru maa n fi waasi rẹ polongo ibo fun Aarẹ Tinubu.
Lẹyin irun ọranyan to ba ki fun awọn eeyan tan ni wọn ni Imaamu Dahiru maa n ṣe waasi ipolongo ibo naa.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alaga igbimọ to n ri si ọrọ mọṣalaṣi Madina, Imam Abubakar Jibrin, sọ pe:
"Iṣoro ti a ni ju pẹlu rẹ ki I ṣe ti pe o n polongo awọn eto Tinubu nikan, amọ o tun maa n ko awọn eeyan jọ siwaju mọṣalaṣi.
"Igba mi-in wa, yoo diidi wọ inu mọṣalaṣi yoo si maa sọrọ oṣelu."
Gbogbo eyi ni Alaga igbimọ to n ri si ọrọ mọṣalaṣi Madina sọ pe o mu kawọn yọ Imaamu Dahiru Abubakar nipo.
"Mo ni kawọn eeyan yee bu Tinubu ni o, pe oun kọ lo fa inira ati aisi aabo fun wa"- Dahiru ti wọn yọ nipo

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ninu alaye tirẹ, Imaamu Dahiru Abubakar ti wọn yọ nipo, sọ pe niṣe loun n fi waasi oun bẹ awọn araalu lati yee bu ẹnu atẹ lu Aarẹ Tinubu.
"Mo maa n rọ awọn eeyan lati yee di ẹbi aisi aabo ati ọrọ aje ti ko daa ru Aarẹ Tinubu.
"Mo tun maa n rọ wọn lati dibo fun un lẹẹkan si I, ki wọn fun un ni anfaani ninu idibo ọdun 2027 lati le tẹsiwaju ninu awọn eto rẹ." (Gẹgẹ bi iwe iroyin Daily Trust ṣe ro o).
Dahiru sọ pe waasi oun maa n da lori ibẹru Ọlọrun, ati ki pe kawọn eeyan yee bu awọn adari lori iṣoro aabo, paapaa Tinubu ti wọn maa n bu ju.
O ni oun maa n sọ fun wọn pe Ọlọrun nikan lo le tan iṣoro ẹda pẹlu adura.
"Mo maa n jẹ ki waasi mi da lori ibẹru Ọlọrun atawọn nnkan ta a n ṣe lojumọ.
" Mo maa n saba ṣe akawe isoro aabo to n waye lawọn orilẹede Africa mi-in bii Sudan, Chad ati Mali, mo si maa n beere pe ṣe Tinubu lo tun fa ai si aabo lawọn ibẹ yẹn naa."
Imaamu ti wọn yọ nipo yii sọ pe oun maa n fi waasi sọ pe apẹẹrẹ opin aye ni awọn ohun to n ṣẹlẹ yii, ki I ṣe ẹjọ Tinubu.
O ni ṣugbọn olootọ ilu ni ika ilu, lo jẹ ki wọn rọ pe waasi ipolongo saa keji fun Tinubu loun n ṣe.



























