‘Mi ò lè ya ìgbẹ́ bìi ti tẹ́lẹ̀ mọ́ láti ìgbà tí wọ́n fi kún iye owó tí à ń san ní yàrá ìgbọ̀nsẹ̀ ìtagbangba’

Aworan
Published

Awọn olugbe ilu kan ti fi aidunnu wọn han si ọwọngogo to de ba lilo yara igbọnsẹ ni awujọ naa.

Eyi ko sẹyin bi awọn alakoso yara igbọnsẹ naa to wa ni Kano ṣe kede pe awọn ti fi ida aadọrin kun iye owo ti awọn eniyan yoo maa san.

Ọkan lara awọn to n lo yara igbonsẹ ọhun to ba BBC Pidgin sọrọ ni ilu Kano ni ọwọngogo naa ko ṣẹyin bi wọn ṣe yọ owo iranwọ kuro lori dollar, ti eleyii si fa ki ọwọngogo gbode kan.

‘’Ki wọn to fi owo kun owo igbọnsẹ, igba mẹta si mẹrin ni mo n lọ si yara igbọnsẹ amọ mo ti mu adinku ba bayii nitori mi o ni owo lati san.’’

O fikun un pe ki wọn to fikun un, N50 naira ni awọn fi n gbọnsẹ amọ nibayii nitori wọn mọ un ni wọn ṣe n gba N70 naira ni ọwọ oun.

‘Idi ti a fi fi owo kun owo ile igbọnsẹ’’

Aworan

Awọn to ni ile igbọnsẹ naa ti sọ idi ti wọn fi fi owo kun owo ti awọn eniyan n san lati lo salanga ati baluwẹ ni ilu naa.

Arakunrin Misbahu Zakariya to ni ile itura fun awọn to ba fẹ gbọnsẹ naa ni ọpọlọpọ nkan lo ti gbe owo leri ni asiko yii.

‘’Ọsẹ ti a ma n ra ni N140-150 tẹlẹ ti gbe owo lori bayii ti wọn si n ta a ni N700.’’

O tun ni yatọ si eyi awọn n san owo omi ati owo igbele naa pẹlu.

‘’Emi naa n san owo ile fun ẹni ti a gba ile lọwọ rẹ, ti a si n san owo omi ni oṣoosu nitori a ko ni ibi ti a ti n pọn omi.’’

Onimọ nipa eto ilera ayika ni ko dara ki awọn eniyan yẹra fun ile itura ati igbọnsẹ nitori ọwọngogo, to si fikun un pe dandan ni awọn eniyan naa yoo wa ibi ti wọn yoo ti lọ tura.

Bakan naa lo rọ ijọba lati pese awọn ile itura ti awọn eniyan ti le gbọnsẹ fun awọn araalu, lati le da abo bo wọn.

Kini ijọba ni awọn yoo se?

Arakunrin Zakari Habu to jẹ alaga ijọba ibilẹ Tarauni ni ilu Kano ni awọn yoo wa ọna atunṣe si isẹlẹ yii.

O ni lootọ ni awọn mọ pe ọwọngogo ti ba ọpọlọpọ nkan ti awọn eniyan n ra.

Amọ wọn ni awọn yoo ba awọn araalu sọrọ to fi mọ awọn to ni awọn ileeṣẹ wọnyii lati rii pe wọn da awọn iye ọja naa pada si eleyii ti ko ni kan ni ni eegun ẹyin.

O kere tan miliọnu 48 ọmọ Naijiria ni wọn yagbẹ si oju popo, ti awọn ọgọọrọ miliọnu miran ko si ni anfaani awọn ile igbọnsẹ to dara.

Eyi ni iwadii ileesẹ imọtoto WASH ti wọn gbe jade ni ọdun 2021.