Àjọ DSS gbé Ladi Adebutu sí àhámọ́

Oríṣun àwòrán, Ogun PDP
Oludije ẹgbẹ oselu PDP nipinlẹ Ogun fun eto idibo gomina ọdun 2023, Ladi Adebutu ti wa ni ahamọ ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ DSS, ẹgbẹ oselu kede.
Akọwe ẹgbẹ naa nipinlẹ Ogun, Kayode Adebayo lo fidi iṣẹlẹ naa mulẹ ninu atẹjade kan to fi síta lọjọ Aje.
Gẹgẹ bii o se salaye, DSS ransẹ pe Adebutu fun ifọrọwerọ pe o lọwọ ninu rogbodiyan to waye lasiko eto idibo ijọba ibilẹ to waye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kọkanla ọdun 2024.
"Eyi ni lati fi to gbogbo ọmọ ẹgbẹ PDP leti pe, otitọ ni pe wọn ti olori ẹgbẹ wa mọ ahamọ DSS fun idi ti a ko ti mọ," Adebayo ṣalaye.
"Ẹwẹ, olori wa ti ni ki a lọ fọkanbalẹ, to si rọ gbogbo ọmọ ẹgbẹ ati awọn alatilẹyin rẹ pe ki wọn ma ṣe jaya.
"Gbogbo ọna ni a sa lati ri pe a gba beeli lọjọ sugbọn pabo lo jaasi; agbẹjọro ti wọn yoo tẹsiwaju ni owurọ ọjọ Isẹgun.
"Atẹjade yii, a fẹ ki awọn eeyan wa ati gbogbo araalu mọ ibi ti olori wa, kí wọn si lọ fọkanbalẹ titi a o fi yanju ọrọ naa."
Ta ni Ladi Adebutu?
Ọgbẹni Ladi Adebutu ni oludije fun ipo gomina lẹgbẹ oṣelu PDP ni ipinlẹ Ogun
Ladi Adebutu kii ṣe ọjẹ wẹwẹ tabi majeṣin ninu ọrọ oṣelu nitori pe o ti le ni ọgbọn ọdun ti o ti n wẹ ninu agbami oṣelu.
Lọdun 1992 lo di ọmọ ile igbimọ aṣofin apapọ Naijiria labẹ ẹgbẹ Social Democratic Party, SDP lati ṣoju ẹkun apapọ Rẹmọ ni ile igbimọ aṣojuṣofin.
O dije fun ijoko ile aṣofian agba labẹ ẹgbẹ oṣelu UNCP lọdun 1998.
Bakan naa lo dije fun ipo aṣofin apapọ lọdun 2003, 2007 ati 2011 labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu PDP.
Lọdun 2015, o wọle gẹgẹbi aṣojuṣofin fun ẹkun apapọ Rẹmọ (ijọba ibilẹ Sagamu, Ikenne ati ariwa Rẹmọ)
Ni ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karun un ọdun 2022 ni wọn yan an gẹgẹ bi oludije fun ipo gomina nipinlẹ Ogun fun ẹgẹ oṣelu PDP.


























