Mo ti gbà láti jẹ́ adele gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo, àmọ́ a kò gbọdọ̀ dẹ́kun àdúrà ìmúláradá fún Akeredolu – Aiyedatiwa

Oríṣun àwòrán, Facebook/Abayomi Adefolalu
Adele gomina ipinlẹ Ondo, Lucky Aiyedatiwa, lo ti rọ awọn eniyan ipinlẹ naa lati tunbọ tẹra mọ adura ti wọn n ṣe fun Gomina Oluwarotimi Akeredolu lori ailera rẹ.
Aiyedatiwa rawọ ẹbẹ yii lakoko to n ba awọn olugbe ipinlẹ naa sọrọ fun igba akọkọ laarọ Ọjọbọ lẹyin to di adele gomina.
Ninu ọrọ rẹ si awọn olugbe ipinlẹ naa, Aiyedatiwa sọ pe alaafia Akeredolu ṣe pataki nitori o jẹ akinkanju olori to mu ayipada rere ba ipinlẹ naa.
O ni “gẹgẹ bi ijọba, a gba pe awọn to dibo fun wa wọle sipo ṣe pataki, a si kabamọ gbogbo ipa ti awọn nnkan to ṣẹlẹ sẹyin ni lori awọn araalu ati idagbasoke ipinlẹ yii.
“Pẹlu gbogbo eleyi naa, ẹyin eeyan mi, mo wa siwaju yin lonii lati rọ yin lati maṣe dawọ adura yin duro gẹgẹ bi ẹ ti n ṣe latẹyin wa, fun imupadabọsipo ni kia ati ilera pipe fun adari wa, Arakunrin Oluwarotimi Akeredolu."
Ọgbẹni Aiyedatiwa sọ pe awọn gbọdọ pada ni kia si oju ọna itẹsiwaju to jina si ipinlẹ Ondo lati bii oṣu diẹ sẹyin.
“A ko le tẹsiwaju ninu iyapa tabi ki onikaluku o maa ṣe tiẹ. A ni lati sọ ara wa di ọkan titi dopin. A ni lati pada wa pẹlu ọwọ agbara ati ipinnu lati mu igbayegbadun ati aabo awọn eeyan wa ni ọkunkundun gẹgẹ bo ṣe wa ninu iwe ofin ilẹ yii ti ọdun 1999.”
Aiyedatiwa sọ pe, ẹru to wuwo ni iṣejọba. eyi ti ẹnikan ko lee da ṣe amọ o gba ajọṣepọ awọn to n ṣe ijọba atawọn ti wọn n ṣejọba le lori.
‘Ohun to ṣẹlẹti re kọja, ẹ jẹ ka tẹsiwaju pẹlu ifẹ’
Adele gomina naa tẹsiwaju pe oun nigbagbọ pe oṣelu awaarawa ri ẹkọ gidi kọ ninu ohun to ṣẹlẹ yii.
"Fun awa ijọba, gbogbo ohun to ṣẹlẹ yii lo yẹ ko ṣi aaye tuntun lọkan wa ti a o fi mọ riri igbagbọ tawọn eniyan ni ninu wa taa o si loo fun igbayegbadun ọpọ eniyan.
“A ni lati foju fo idaamu ari rogbodiyan to ti rekọja ki a si gbaruku ti ṣiṣẹ iṣẹ sin awọn araalu nitori afunṣọ lasan ni a jẹ.
“Ana ti re kọja. Asiko ti to lati tẹsiwaju pẹlu ifẹ, iṣọkan, ati afojusun to lọọrin ti gomina ipinlẹ yii ni.
“Mo waa bẹ gbogbo awọn to wa ni iṣejọba ipinlẹ Ondo fun atilẹyin tootọ, ajọṣepọ to yaayi ati ifarajin. A nilo irẹpọ tuntun lati lee lepa ero rere gomina ki a si muu wa si imuṣẹ.
“Ẹyin eyan mi nipinlẹ Ondo, ifasẹyin kekere ni ohun to ṣẹlẹ sẹyin, a ti gbera sọ gẹgẹ bi ijọba."
Ṣaaju ni ọrọ bi Lucky Aiyedatiwa yoo ṣe jẹ adele gomina ipinlẹ Ondo, ti fa ede aiyede nipinlẹ naa, paapaa laarin awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress.
Koda, Aarẹ Bola Tinubu ba wọn da si ọrọ naa, ko to o di pe o yanju.
Ṣugbọn, ni ọjọ Iṣẹgun, ọjọ kejila, oṣu Kejila, ọdun 2023, ni Akọwe gomina ipinlẹ naa, Richard Olatunde, kede pe Gomina Akeredolu ti fọwọ si ki Aiyedatiwa dele de e, bo ṣe n lọ fun itọju ara rẹ.
























