Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo já ipò olùkọ́ mẹ́fà sílẹ̀ nítorí wọ́n ṣe aṣemáṣe ìdánwò

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti kede irẹsilẹ ipo awọn olukọ mẹfa kan lori ipa ti wọn ko nibi aṣemaṣe idanwo akọjade iwe mẹwaa WAEC lọdun 2022.
Ajọ to n ṣe akoso eto ẹkọ n'ipinlẹ naa, TESCOM, lo sọ ọrọ yii di mimọ.
Nipasẹ iwe aṣẹ kan ti alaga ajọ naa, Orowale M buwọlu ti wọn si fi ranṣe si adari agba to n mojuto eto ẹkọ ni agbegbe Ṣaki n'ipinlẹ Ọyọ lo ti finọrọ naa lede.
Ajọ naa ni igbesẹ lati rẹ ipo awọn olukọ ọhun silẹ lo waye lẹyin ti iṣẹ iwadii fi idi rẹ mulẹ wi pe gbogbo wọn lo jẹbi ẹsun aṣemaṣe idanwo.
Akọsilẹ awọn olukọ naa ni, Ogunkunle Musibau O ti wọn ja lati ipele ikẹrinla si ikẹtala

Oríṣun àwòrán, VON
Bẹẹ naa ni wọn ja Popoola Akeem Abiola silẹ lati ipele ikẹjọ si ikeje, lati ile ẹkọ girama 'Owo Community Grammar School', Owo.
Lara awọn olukọ mii ti wọn tun rẹ ipo wọn silẹ ni, Ogunkunle Musibau O, lati ipele ikẹrinla si ikẹtala, ati Popoola Akeem Abiola lati ipele ikẹjọ si ikeje lati ile ẹkọ girama 'Owo Community Grammar School', Owo.
Bakan naa ni wọn ja ipo Mustapha Bolanle Nureni lati ipele ikẹẹdogun si ikẹrinla, Ahmed Adamu Ademola lati ipele ikẹẹwa si ikẹẹsan, Titilola Ajeleye John lati ipele ikẹẹwa si ikẹẹsan.
Ẹni to kẹyin ni Adegbola Abraham Titilope lati ipele ikẹjọ si ikeje lati ile ẹkọ girama 'Progressive Secondary Grammar School', Tede.























