Ìjọba ìpínlẹ̀ Ogun kẹ́dùn ikú Ijalaye, ọ̀gá àjọ INEC Ogun tó kú lẹ́yìn ìpàdé l‘Abuja

Aweoran Oloogbe Olaniyi Ijalaye

Oríṣun àwòrán, INEC OGUN

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun, ti kẹdun iku ọga agba INEC Ogun, Amofin Olayi Ijalaye, ẹni to jade laye lẹyin ipade, n’irọlẹ ọjọ Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ ọdun 2024.

Owurọ kutu ọjọ Iṣẹgun, ogunjọ oṣu kẹjọ ọdun yii ni iroyin jade, pe alabojuto ileeṣẹ eleto idibo ilẹ wa, INEC, ẹka tipinlẹ Ogun, naa jade laye l’Abuja.

Iroyin sọ pe kinni kan ko ṣe alabojuto eto idibo Ogun ṣiwaju ipade yii, koda, o kopa daadaa pẹlu ilera to peye ninu ipade ti wọn ṣe ni olu ileeṣẹ INEC l’Abuja naa.

Ọga agba pata fun ajọ INEC,Ọjọgbọn Mahmood Yakubu,lo ṣe alaga ipade naa, eyi to da lori ibo ipinlẹ Edo ati Ondo.

Lẹyin ipade ni ọmọ bibi ipinlẹ Ondo naa pada si yara ile itura to de si, ibẹ la gbọ pe o ti ṣubu lulẹ, ti ọlọjọ si de.

Ninu atẹjade ibanikẹdun ti Gomina Abiodun fi sita lọjọ Iṣẹgun, o ṣapejuwe iku Ijalaye bii eyi to ba gbogbo eeyan lojiji.

Abiodun sọ pe akikanju eeyan to jafafa, amoye ti ki i fi iṣẹ ṣere ni Oloogbe Niyi Ijalaye.

Gomina sọ pe adanu nla ni iku rẹ jẹ lai ni iye meji ninu rara.

‘’Mo ba gbogbo iran Ijalaye kẹdun, pẹlu awọn eeyan ipinlẹ Ondo ati ijọba ibẹ, lori iku ọmọ wọn pataki, Amofin Niyi Ijalaye.

Awokọse ni, olootọ ti ko fiṣẹ ṣere ni. Bi iku rẹ si ṣe dun wa to, ohun to n tu wa ninu ni pe igbesi aye rere ni Niyi Ijalaye gbe, igbesi aye ọmọluabi to lapẹẹrẹ si ni pẹlu. Ki Oluwa tẹ ẹ si afẹfẹ rere’’

Bẹẹ ni atẹjade ti Gomina Ogun, Dapo Abiodun, fi sita ṣe wi.

Ta a ni Olóògbé Niyi Ijalaye?

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu keji ọdun 2022 ni wọn gbe Olaniyi Ijalaye wa si ipinlẹ Ogun, lati rọpo Ṣegun Agbaje ti i ṣe alabojuto INEC ipinlẹ naa nigba yẹn.

Ilu Eko ni wọn gbe Agbaje lọ, ti Ijalaye si bẹrẹ iṣakoso tirẹ ni ọfiisi INEC to wa ni Magbon, l’Abeokuta.

Ileewe giga Obafemi Awolowo to wa ni Ile-Ife ni Ijalaye ti kẹkọọ ninu imọ ofin, o gboye akọkọ ni ọdun 1982, o si gba ti ipele keji ni ọdun 1995.

Ọdun 1983 ni wọn sọ ọ di amofin orilẹede Naijiria.

Oloogbe Olaniyi Ijalaye darapọ mọ ileefowopamọ First bank gẹgẹ bii oṣiṣẹ to n ri si ọrọ ofin ni banki naa, iyẹn ni 1984.

Ọdun 2011 lo fẹyinti lẹnu iṣẹ naa, lẹyin to ṣiṣẹ fun ọdun mejidinlọgbọn gbako, ipo Igbakeji adari ofin ni Oloogbe Ijalaye wa to fi f’ẹyinti.

Ọjọgbọn Mahmood Yakubu, ọga agba INEC, bura fun un si ipo komiṣanna eto idibo Ogun loṣu keji ọdun 2022, o si dagbere fun aye lọjọ kọkandinlogun, oṣu kẹjọ, ọdun 2024.

Oṣu kọkanla odun 2024 yii ni Oloogbe ko ba pe ẹni ọdun merindinlaadọrin (66)

Àwọn oloṣelu to di oloogbe ni 2024

Ni 2024 yii, iṣẹlẹ iku awọn oloṣelu kan gbode, lara wọn ni:

*Sẹnetọ Ifeanyi Ubah

Ẹni to n ṣoju Guusu ipinlẹ Anambra ṣaaju iku rẹ.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu keje ọdun 2024 yii ni ọkunrin naa ku lorilẹede UK.

Ọnarebu Isa Dogonyaro

Ẹni ọdun mẹrindinlaaadọta (46) ni Oloogbe Isa Dogonyaro nigba to ku lọjọ kẹwaa, oṣu karun-un ọdun 2024.

Agbegbe Babura/ Garki, ni ipinlẹ Jigawa, ni oloogbe naa ṣoju fun ni ile igbimọ aṣofin agba.

Ọnarebu Olajide Akinremi

Ẹkùn Ariwa Ibadan ni Oloogbe Olajide Akinremi tawọn eeyan mọ si Jagaban, ṣoju fun ni ile igbimọ Aṣojuṣofin.

Oloṣelu ọmọ ilu Ibadan naa ko ṣe aarẹ tẹlẹ ko too di oloogbe lojiji ni ilu Abuja, loṣu keje ọdun 2024.

Ọnarebu Ekene Adams

Ẹni ọdun mọkandinlogoji (39) ni Oloogbe Ekene Adams nigba to jade laye lọjọ kẹrindinlogun, oṣu keje ọun 2024.

Oloogbe Ekene Adams lo n ṣoju Chikun/ Kajuru, ipinlẹ Kaduna, ni ile igbimọ Aṣojuṣofin, ki ọlọjọ too de si i .