Ìdí rèé tí àwa aṣòfin ṣe fẹ́ ra ọ̀kọ̀ bọ̀gìnnì fún ara wa, àwọn sẹ́nẹ́tọ̀ ṣàlàyé

Oríṣun àwòrán, Godswill Akpabio/Facebook
Ile aṣofin agba niluu Abuja ti ṣalaye idi tàwọn ọmọ ilè igbimọ aṣofin agba ṣe fẹ ra ọkọ bọginni fun ara.
Ọrọ ọkọ naa l'awọn araalu ti bu ẹnu ẹtẹ lu eleyii ti wọn sọ pe ifowoṣofo ni o tumọ sí.
Ohun ti a n gbọ ni pe ọgọjọ miliọnu(N160m) ni ẹyọkọọkan ọkọ naa yoo bade.
Ohun ti a n gbọ ni pe ọgọjọ miliọnu(N160m) ni ẹyọkọọkan ọkọ naa yoo bade.
Amọ, alaga igbimọ to n ri si oniruuru iṣẹ nile asofin agba l'Abuja, Sẹnẹtọ Sunday Karimi sọ fawọn akọroyin pe awọn adari ile igbimọ aṣofin agba mejeeji pinnu lati ra awọn ọkọ bọginni yii tori wọn n fẹ ọkọ ti yoo le rìn daadaa pẹlu bi oju titi Naijiria ṣe ri.
Ati pe awọn fẹ ra iru ọkọ tàwọn le lo fun ọdun mẹrin ti yoo si dun un wo.
"Awọn ohun ti a ro niyii ti a fi pinnu lati ra ọkọ ti owo rẹ wọn ti a le ri lo daadaa.
Ati wi pe ọrọ ọkọ rira fawọn aṣofin kii ṣe tuntun.
Ọdun mẹrin mẹrin ti awọn aṣofin tuntun mii ba ti dibo wọlé ni wọn maa n ra ọkọ tuntun," Sẹnẹtọ Karimi ṣalaye.
Ọpọ ọmọ Naijiria lo ti n pariwo lori ìpinnu ile igbimọ aṣofin agba lati ra ọkọ olowo iyebiye fun ara wọn, pẹlu bi gbogbo nkan ṣe wọn gogo bayii ni Naijiria.
Sẹnẹtọ 109 lo wa ni ile aṣofin agba niluu Abuja nigba ti 360 aṣofin wa ni ile igbimọ aṣoju-ṣofin ti awọn mejeeji sí jẹ 469 lapapọ.
Àwa máa gba ọkọ̀ SUV tí ìjọba fẹ́ rà fún wa, iṣẹ́ ìlú la fẹ́ fi ṣe - Àwọn aṣòfin Labour Party fún alága lésì

Oríṣun àwòrán, X
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party tí wọ́n jẹ́ ọmọ aṣòfin ní ilé igbimọ aṣòfin àgbà ní Abuja ti kọtí ọ̀gbọ̀in sí ìkílọ̀ alága ẹgbẹ́ náà, Julius Abure láti má gba ọkọ̀ bọ̀gìnì tí ìjọba ń gbèrò láti rà fún àwọn aṣòfin.
Ní ọjọ́ Ajé, ọjọ́ Kérìndínlógún oṣù Kẹwàá ni Abure fi àtẹ̀jáde kan síta pé níbi tó ti ní àwọn adarí ilé aṣòfin ń gbèrò láti ra ọkọ̀ bọ̀gìnì SUV tí iye rẹ̀ tó ọgọ́jọ mílíọ̀nù náírà fún aṣòfin kọ̀ọ̀kan.
Abure tó júwe èròńgbà náà láti ra ọkọ̀ fún àwọn aṣòfin náà bí ìgbà tí ìjóba kò mọ ohun tó kàn pẹ̀lú bí gbogbo nǹkan ṣe rí ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ní àsìkò yìí.
Ó ní kò yẹ kí àwọn aṣòfin náà le ronú láti ra ọkọ̀ olówó iyebíye lásìkò tí ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà ti dẹnu kọlẹ̀ pátápátá, tó sì rọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Labour Party tó wà ní ilé aṣòfin náà láti má gba ọkọ̀ náà.
Àmọ́ nígbà tí àwọn akọ̀ròyìn bá àwọn aṣòfin tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú Labour Party láti mọ ìhà tí wọ́n kọ sí àrọwà alága wọn yìí, ọ̀pọ̀ nínú wọn ló ní àwọn máa gba ọkọ̀ náà.
Aṣòfin Ngozi Okolie tó ń ṣojú ẹkùn àríwá àti gúúsù Delta Aniocha nílé aṣòfin àgbà ní nǹkan tí Abure sọ kò lè ṣeéṣe nítorí kò sí bí àwọn yóò ṣe máa ṣe iṣẹ́ àwọn láìsí ọkọ̀.
Okolie ní ọkọ̀ SUV tí wọ́n fẹ́ rà fún àwọn wà fún pé kí àwọn lè máa ṣiṣẹ́ àwọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ́ àti pé tí Abure kò bá fẹ́ kí àwọn gba ọkọ̀ náà ó ní láti pèsè ọkọ̀ mìíràn fún àwọn.
“Lóòótọ́ ni ètò ọrọ̀ ajé Nàìjíríà dẹnu kọlẹ̀ àmọ́ ọkọ̀ kan fún aṣòfin kò ì tíì pọ̀ jù, ohun tí a nílò ni.”



























