2023 elections: Attahiru Jega ní ìdìbò ọdún 2023 lè má wáyé pẹ̀lú bí ǹkan ṣe ń lọ ní Nàìjíríà báyìí

Oríṣun àwòrán, Inec
Alaga ajọ INEC tẹlẹ, Ọjọgbọn Attahiru Jega ti kilọ pe eto idibo gbogbogbo ọdun 2023 le ma waye pẹlu eto abo to mẹhẹ kaakiri orilẹede Naijiria.
Jega to sọrọ yii nigba to n sọrọ apilẹkọ nibi ayẹyẹ iranti ati ọjọ ibi ọdun kejilelaadọrin gomina ipinlẹ Oyo tẹlẹ to ti di oloogbe, Abiola Ajimobi niluu Ibadan.
Alaga ajọ INEC tẹlẹ ni nkan ko fara rọ pẹlu eto ni Naijiria lọwọ yii.
- Kìí ṣe Tinubu ló kọ́ ilé tí mò ń gbé fún mi, GTB ló yá mi lówó tí mo fi parí ilé náà - Ayo Adebanjo
- Wo ibi tí wọ́n ti ń sun ẹran èèyàn jẹ bí ẹran ìgbẹ́ tí ọwọ́ àjọ DSS tẹ èèyàn 30 lára wọn
- Èmi àti ọmọ ẹgbẹ́ akọrin wa jọ yó ìfẹ́ ara wa ni - Pásítọ̀ ní òun kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábáni lòpọ̀
- Ta ni Ọba Sátánì tó fẹ́ ìyàwó 57 kó tó jáde láyé lẹ́ni ọdún 74?
- Idán oríta nínú ṣọ́ọ̀ṣì Winners Chapel, okùnrin kan kù gììrì mọ́ Bíṣọ́ọ̀bù Oyedepo lórí pẹpẹ ìwàásù
- Obìnrin kan tó ti Ìnsìpẹ́kítọ̀ Ọlọ́pàá ṣubú lulẹ̀ kàgbákò, ó dèrò ilé ẹjọ́ Badagry
- Wo bí wọ́n ṣe sin Ọba Satani pẹ̀lú ọkọ̀ àti orin tó fẹ́ràn jù
Ọjọgbọn Jega ni ijọba ni lati wa ojutu si eto abo to mẹhẹ tori o le ṣakoba nla fun eto idibo lọdun 2023.
O ni ti eto idibo ko ba waye ni alaafia lai si rogbodiyan, awuywuye to maa tibẹ jade ti maa pọju.
Jega ni eto abo to mẹhẹ yoo ṣakoba fun igbaradi fun eto idibo ati idibo gan an.
Alaga INEC tẹlẹ ni iru esi ibo to ba jade nibi ti rogbodiyan ba ti bẹ silẹ ko le wa ni ibamu pẹlu ofin.
''Bi a ti n wo eto idibo ọdun 2023 niwaju, ẹru n ba ọpọ eeyan pẹlu eto abo to ti di oju keji bayii.
Ti a ko ba le wa wọrọkọ fi ṣe ada lori ọrọ eto abo yii, afaimọ ko ma dena eto idibo ọhun gan an.
Eto idibo gbogbo ọdun 2007 ni o buru julọ pẹlu eeru nitori awọn ẹṣọ eleto abo ṣiṣẹ fawọn oloṣelu to lo wọn,'' Jega lo sọ bẹẹ.
Ẹwẹ, igbakeji aarẹ Yemi Osinbajo to jẹ alaga ijoko nibi eto naa ni ijọba awarawa si lo gbayi julọ lagbaye.
Osinbajo ni ohun kan to ṣe pataki ni pe awọn eeyan gbọdọ lanfaani lati yan ẹni to ba wu wọn sipo.























