Ondo election 2020: Igbákejì gómìnà Ondo, Agboola Ajayi ní lóòtọ́ lòun fẹ́ f'ẹgbẹ́ PDP sílẹ̀ láti jẹ́'pè aráàlú ṣùgbọ́n...

Published

Kii ṣe pe o ṣa dede wu igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, awọn eeyan ni wọn n gun un ni kẹṣẹ pe ko fi ẹgbẹ oṣelu naa silẹ.

Igbakeji gomina ipinlẹ Ondo, Agboọla Ajayi ṣalaye pe awọn araalu ni ipinlẹ Ondo ni wọn fẹ ki oun wa oko miran ṣan ki ala rẹ lati di gomina ipinlẹ naa lee ṣẹ.

Ninu ifọrọwerọ pẹlu BBC News Yoruba, agbẹnusọ fun Agboọla Ajayi, ọgbẹni Ọkẹowo ni lẹyin ti esi ibo abẹle ẹgbẹ oṣelu ni ipinlẹ Ondo ti waye ti Jẹgẹdẹ si ti wọle lo ti gba fun Ọlọrun to si ti kii ku orire.

Amọṣa igbe 'awọn eeyan ẹkun gusu ipinlẹ Ondo atawọn majẹobajẹ kan ni ipinlẹ naa ni o mu ki O bẹrẹ ijiroro ati igbesẹ lati kuro ni ẹgbẹ oṣelu PDP'

Gẹgẹ bi o ṣe sọ, igbakeji gomina ipinlẹ Ondo naa ko tii kuro ni ẹgbẹ oṣelu PDP ṣugbọn yoo ṣi kuro titi opin ọsẹ yii.

Ni owurọ ọjọ Iṣẹgun ni iroyin gbode kan pe awọn iwe ipolongo ibo kan to jẹ ti Ọgbẹni Agboọla Ajayi labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu ZLP ti wa kaakiri igboro ilu Akurẹ tii ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo.

Igun igbakeji gomina Ondo, Agboọla Ajayi ṣalaye pe eyi ko ṣokunkun si awọn nitoripe ọbẹ to dun ni Agboọla Ajayi gbogbo awọn ẹgbẹ oṣelu lo si fẹ bula nibẹ.

Agbẹnusọ fun Oloye Agboọla Ajayi, ọgbẹni Ọkẹowo fi kun un pe kii ṣe ẹgbẹ oṣelu ZLP nikan lo ti ṣe iwe pelebe ipolongo idibo pẹlu aworan rẹ, o ni awọn ẹgbẹ oṣelu miran bii ADC, AA pẹlu fẹ gboriwọle.

Amọ o, o ni igbakeji gomina ipinlẹ Ondo ọhun ko ti fẹnuko lori ibi gan an to fẹ lọ nibẹ.

"Nigba ti a o ba fi ri opin ọsẹ yii, Agboọla Ajayi yoo kede ibi to fẹ lọ, ṣugbọn o daju pe yoo fi ẹgbẹ oṣelu PDP silẹ"