Yoruba Film: Ṣé ẹ máa wá ní Pasuma ni mo bí àwọn ọmọ mi tó ń jẹ́ Kuti fún - Jaiye

Oṣere Jaiye Kuti

Oríṣun àwòrán, jayeola_monje

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Lori ọrọ ti awọn eniyan ma n sọ pe awọn ọga ọkunrin ninu iṣẹ tiata ma n bere ibalopọ ki wọn to fun wọn ni isẹ, Jaye Kuti ni ko si otitọ kankan nibẹ.

Amọ o fi kun un wi pe, ẹni to ba n wa ifa, ti oun yọju si oun ti ko kan an ni wọn ma n fi ilọkulọ lọ.

Gbajúgbajà òsèré Nollywood, Jaye Kuti wa parọwa si awọn eniyan papa awọn to fẹran iṣẹ tiata lati ni suuru ni idi iṣẹ wọn, ti wọn si mu iṣẹ wọn ni ọkunkundun.