Direct Primaries: Ilé ìgbìmọ̀ asòfin méjèèjì l'Abuja fẹnukò lórí ìdíbò olójúkojú nínú ẹgbẹ́ òṣèlú

Published

Ile ìgbìmọ̀ asòfin àgbà tí buwọ́lu ìwé abadofin tí àwọn ọmọ ilé méjèèjì fenukò sì lórí ìdìbò abẹ́lé fáwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ni Nàìjíríà.

Ìbuwolù yìí wáyé lẹ́yìn èsì àbájáde ìgbìmọ̀ tí ilé méjèèjì gbé dìde lórí abadofin náà .

Ìfẹnukò ilé méjèèjì ní pe ki awon ẹgbẹ́ òṣèlú máa ṣe ìdìbò abẹ́lẹ́ láti yan ẹniti yóò ba du ipò ìdìbò kankan láwùjọ ni ojúkojú yàtọ̀ sí èyí tí wọn máa ń ṣe tẹ́lẹ̀ níbi tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ yóò kọ́kọ́ yàn àwọn tí yóò lọ dibò.

Ṣáájú ni ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ asòfin Nàìjíríà Ahmed Lawan tí kọ́kọ́ gbé ìgbìmọ̀ eléni méje kan dìde nínú oṣù Kẹ̀wá ọdún yìí láti ṣe agbeyẹwo ilé igbimọ̀ asòfin méjèèjì kí wọn tó gbé e síta.

Ṣáájú ni Abẹnugan ilé ìgbìmọ̀ aṣojú ṣòfin, Femi Gbajabiamila tí ṣàlàyé pé àwọn náà faramọ́ ìlànà eto ìdìbò abẹ́lẹ́ yìí fún itesiwaju ìjọba awa arawa tó yẹ kooro.

Senetọ̀ Yahaya Abdullahi tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ náà sọ pé lẹ́yìn tí ilé bá ti jan an lontẹ tí ààrẹ Muhammadu Buhari bá sì ti buwọ́lu, wọn ò lọ fún Ètò ìdìbò ijoba àpapọ̀, tí ìpínlẹ̀ àti ti ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ tí yoo wáyé n'ilu Abuja láìpẹ́ yìí.

Lásìkò to ń dáhùn ìbéèrè láti ọ̀dọ̀ àwọn oníroyìn, olùbádàmọ̀ran pàtàkì fún ààrẹ Buhari lórí ọ̀rọ̀ òṣèlú, Baba Femi Ojodu sọ pé òun gbé orí yín fún àwọn adarí ẹgbẹ́ òṣèlú gbogbo fún Ìfẹnukò àti ìfọwọ́sọwọ́pọ̀ tó mú kí òfin náà ṣe é ṣe.

Ó ní àbájáde ìpàdé náà sọ èso rere fún ètò oselu ìjọba àwa arawa l'ábẹ́lẹ́ pàápàá julọ ninu egbe oselu APC.

Ó ní ìgbàkejì ààrẹ, ọ̀jọ̀gbọ́n Yemi Osinbajo pé ìpàdé láti jẹ́ kí gbogbo àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú sọ èrò wọn kì wọn sì jó fi ẹnu kò fún ìlọsíwájú orile-ede.