Covid-19: ìjọba Nàìjíríà ti gbé nọ́mbà ìwé ìrìnà àwọn arìnrìn àjò ti 100 ti wọ́n fòfin de jáde

Published
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Ìgbìmọ̀ amúṣẹ́ṣe ààrẹ lórí Covid-19 (PTF), ìyẹn ìgbìmọ náà wà fún sísọ ìlànà ètò ìjọba láti dẹ́kun ìtànkálẹ̀ ààrùn Covid-19, ti fí nọ́mbà ìwé ìrìnà ènìyàn ẹgbẹ̀rún ti kò tẹ̀lé ìlànà ìjọba lórí ìrìn àjò síta.

Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ alága PTF lórí Covid-19, Boss Mustapha ló buwọ́lu ìwé náà tí ó fi gbé nọ́mbà ìwé ìrìnà àwọn ènìyàn náà síta lójú òpó Twitter rẹ.

Ó ní àwọn ọgọ́rùn náà ni wọ́n kọ̀ láti tẹ̀lé òfín ìrìn àjò láti ilẹ̀ òkèrè pàápàá jùlọ láti lo oṣẹ̀ kan lẹ́yin ti wọ́n ṣe àyẹwo Covid -19 ki wọ́n tó rìnrìn àjò.

Oṣù mẹ́fà gbáko ni wọ̀n kò fi ni le rìnrin ajo, bẹ̀rẹ̀ láti Ọjọ́ Kíní, Oṣù Kíní sí ọgbọ̀n ọjọ́, Oṣù kẹfà, ọdún 2021, èyí túmọ̀ sí pé, àwọn ènìyàn yìí kò ni lé kúro ni Nàìjíríà ní gbogbo àsìkò yìí

Ìgbìmọ̀ PTF fikuN pé àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ti ọ̀rọ̀ kàn létí, àti pé wọ́n kò ni le fi ìwé ìrìnà náà rin ìrìn àjò lọ sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.

Ìgbìmọ̀ ọ̀hún ti sọ sáájú pé, àwọn yóò dá ṣẹ̀ríà fún àwọn ti kò bá tẹ̀lé àwọn ìlànà Covid-19 àti pé ọwọ́jà ààrùn Covid-19 ẹlẹ́kèejì ni Nàìjíríà ń bá fíra lọ́wọ́.

Lọ́wọ́lọ́wọ́, ọ ti lé ni ẹgbẹ̀rún márùndíláádọ́rùn ènìyàn tó ti ni ààrùn náà ni Nàìjíríà gẹ́gẹ́ bi àjọ NCDC ṣe sọ